AISAYA 38

38
Àìsàn Hesekaya ati Ìmúláradá Rẹ̀
1Ní àkókò náà, Hesekaya ṣàìsàn, àìsàn náà pọ̀; ó fẹ́rẹ̀ kú. Aisaya wolii, ọmọ Amosi tọ̀ ọ́ wá ní ọjọ́ kan, ó wí fún un pé: “OLUWA ní kí n sọ fún ọ pé kí o ṣe ètò ilé rẹ, nítorí pé o óo kú ni, o kò ní yè.”
2Hesekaya bá kọjú sí ògiri, ó gbadura sí OLUWA, 3ó ní, “OLUWA, dákun, mo bẹ̀ ọ́ ni, ranti bí mo ti ṣe fi tọkàntọkàn rìn níwájú rẹ pẹlu òtítọ́ inú, tí mo sì ṣe ohun tí ó tọ́ lójú rẹ.” Hesekaya bá sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn.
4OLUWA bá sọ fún Aisaya pé 5kí ó lọ sọ fún Hesekaya pé, òun, OLUWA Ọlọrun Dafidi baba ńlá rẹ̀ ti gbọ́ adura rẹ̀. Oun ti rí omijé rẹ̀, òun óo sì fi ọdún mẹẹdogun kún ọjọ́ ayé rẹ̀. 6OLUWA ní òun óo gba Hesekaya lọ́wọ́ ọba Asiria, òun óo gbèjà ìlú Jerusalẹmu, òun óo sì dáàbò bò ó.
21Aisaya bá sọ fún Hesekaya pé kí wọn bá a wá èso ọ̀pọ̀tọ́ kí wọn lọ̀ ọ́, kí wọn fi lé ojú oówo tí ó mú un, kí ó lè gbádùn.
22Hesekaya bá bèèrè pé, kí ni àmì tí òun óo fi mọ̀ pé òun óo tún fi ẹsẹ̀ òun tẹ ilé Olúwa? 7Aisaya ní, àmì tí OLUWA fún Hesekaya tí yóo mú kí ó dá a lójú pé òun OLUWA yóo ṣe ohun tí òun ṣèlérí nìyí:#38:21-22 A ti yọ ẹsẹ 21 ati 22 wá sáàrin ẹsẹ 6 ati 7. (Wo 2A. Ọba 20:6-7.) 8Òun óo mú kí òjìji oòrùn ìrọ̀lẹ́ pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá lórí àtẹ̀gùn Ahasi. Oòrùn bá yí pada nítòótọ́, òjìji sì pada sẹ́yìn ní àtẹ̀gùn mẹ́wàá tí ó ti sọ tẹ́lẹ̀.
Orin Ọpẹ́ tí Hesekaya kọ
9Orin tí Hesekaya ọba Juda kọ sílẹ̀ nígbà tí ó ṣàìsàn tí Ọlọrun sì wò ó sàn nìyí:
10Mo ti rò pé n óo kú lọ́jọ́ àìpé,
ati pé a óo sé mi mọ́ inú ibojì,
níbẹ̀ ni n óo sì ti lo ìyókù ọjọ́ ayé mi.
11Mo rò pé n kò ní tún fojú kan OLUWA mọ́ ní ilẹ̀ alààyè,
ati pé n kò ní sí láàyè mọ́
láti tún fi ojú mi kan ẹnikẹ́ni.
12A tú àgọ́ mi palẹ̀ bí àgọ́ darandaran,
a sì ká a lọ kúrò lọ́dọ̀ mi.
Mo ká ayé mi bí aṣọ tí wọn ń hun.
Ó sì gé mi kúrò bí aṣọ tí wọ́n gé kúrò lórí òfì.
Mo ti kọ́ rò pé tọ̀sán-tòru ni ìwọ OLUWA ń fi òpin sí ayé mi.
13Mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́ títí ilẹ̀ fi mọ́
ó fọ́ gbogbo egungun mi bí kinniun ti máa ń fọ́ egungun.
Tọ̀sán-tòru mo rò pé Ọlọrun ń fi òpin sí ayé mi ni.
14Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀,
mò ń ké igbe arò bí àdàbà.
Mo wòkè títí ojú ń ro mí,
ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.
15Ṣugbọn kí ni mo lè sọ?
Nítorí pé ó ti bá mi sọ̀rọ̀,
òun fúnrarẹ̀ ni ó sì ṣe é
Oorun kò kùn mí nítorí pé ọkàn mi bàjẹ́.
16OLUWA, nǹkan wọnyi ni ó mú eniyan wà láàyè,
ninu gbogbo rẹ̀ èmi náà yóo wà láàyè.
Áà, jọ̀wọ́ wò mí sàn, kí o mú mi wà láàyè.
17Nítorí ìlera mi ni mo ṣe ní ìbànújẹ́ lọpọlọpọ;
ìwọ ni o dì mí mú,
tí n kò fi jìn sinu kòtò ìparun,
nítorí o ti sọ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi di ohun ìgbàgbé.
18Ibojì kò lè dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ,#Sir 17:27; Bar 2:17
bẹ́ẹ̀ ni ikú kò lè yìn ọ́;
kò sí ìrètí mọ́ fún àwọn tí wọ́n ti lọ sinu isà òkú,
wọn kò lè gbẹ́kẹ̀lé òdodo rẹ mọ́.
19Alààyè, àní alààyè, ni ó lè máa yìn ọ́
bí mo ti yìn ọ́ lónìí.
Baba a máa kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, nípa òdodo rẹ.
20OLUWA yóo gbà mí là,
a óo fi àwọn ohun èlò orin olókùn kọrin ninu ilé OLUWA,
ní gbogbo ọjọ́ ayé wa.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 38: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa