AISAYA 29

29
Òkè Sioni Ìlú Dafidi
1Ó ṣe fún Arieli, Jerusalẹmu, ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun!
Ìlú tí Dafidi pàgọ́ sí.
Ẹ ṣe ọdún kan tán, ẹ tún ṣe òmíràn sí i,
ẹ máa ṣe àwọn àjọ̀dún ní gbogbo àkókò wọn.
2Sibẹsibẹ n óo mú ìpọ́njú bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun.
Ìkérora ati ìpohùnréré ẹkún yóo wà ninu rẹ̀,
bíi Arieli ni yóo sì rí sí mi.
3N óo jẹ́ kí ogun dó tì yín yíká
n óo fi àwọn ilé ìṣọ́ ka yín mọ́;
n óo sì mọ òkítì sára odi yín.
4Ninu ọ̀gbun ilẹ̀ ni a óo ti máa gbóhùn rẹ̀,
láti inú erùpẹ̀ ni a óo ti máa gbọ́, tí yóo máa sọ̀rọ̀.
A óo máa gbọ́ ohùn rẹ̀ láti inú ilẹ̀ bí ohùn òkú,
a óo sì máa gbọ́ tí yóo máa sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ láti inú erùpẹ̀.
5Àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóo pọ̀ bí iyanrìn,
ogunlọ́gọ̀ àwọn aláìláàánú yóo bò ọ́ bí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ lọ.
6Lójijì, kíá,
OLUWA àwọn ọmọ ogun yóo dé ba yín,
pẹlu ààrá, ati ìdágìrì, ati ariwo ńlá;
ati ààjà, ati ìjì líle,
ati ahọ́n iná ajónirun.
7Ogunlọ́gọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bá ìlú tí ń jẹ́ pẹpẹ Ọlọrun jà,
yóo parẹ́ bí àlá,
gbogbo àwọn tí ń bá ìlú olódi rẹ jà,
tí wọn ń ni í lára yóo parẹ́ bí ìran òru.
8Bí ìgbà tí ẹni tí ebi ń pa bá lá àlá pé òun ń jẹun,
tí ó jí, tí ó rí i pé ebi sì tún pa òun,
tabi tí ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ́ lá àlá
pé òun ń mu omi
ṣugbọn tí ó jí, tí ó rí i pé òùngbẹ ṣì ń gbẹ òun,
bẹ́ẹ̀ ni yóo rí fún ogunlọ́gọ̀ orílẹ̀-èdè tí ń bá Jerusalẹmu jà.
Ìkìlọ̀ tí A kò Náání
9Ẹ sọ ara yín di òmùgọ̀,
kí ẹ sì máa ṣe bí òmùgọ̀.
Ẹ fọ́ ara yín lójú
kí ẹ sì di afọ́jú.
Ẹ mu àmuyó, ṣugbọn kì í ṣe ọtí.
Ẹ máa ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n láì mu ọtí líle.
10Nítorí OLUWA ti fi ẹ̀mí oorun àsùnwọra si yín lára#Rom 11:8
Ó ti di ẹ̀yin wolii lójú;
ó ti bo orí ẹ̀yin aríran.
11Gbogbo ìran yìí sì ru yín lójú,
bí ọ̀rọ̀ inú ìwé tí a fi èdìdì dì.
Nígbà tí wọ́n gbé e fún ọ̀mọ̀wé
tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”
Ó ní òun kò lè kà á
nítorí pé wọ́n ti fi èdìdì dì í.
12Nígbà tí wọ́n gbé e fún ẹni tí kò mọ̀wé
tí wọ́n ní, “Jọ̀wọ́ bá wa kà á.”
Ó ní òun kò mọ̀wé kà.
13OLUWA ní,#Mat 15:8-9; Mak 7:6-7
“Nítorí pé ẹnu nìkan ni àwọn eniyan wọnyi fi ń súnmọ́ mi,
ètè lásán ni wọ́n sì fi ń yìn mí;
ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí mi.
Òfin eniyan, tí wọn kọ́ sórí lásán, ni ìbẹ̀rù mi sì jẹ́ fún wọn.
14Nítorí náà n óo tún ṣe ohun ìyanu sí àwọn eniyan wọnyi,#1 Kọr 1:19
ohun ìyanu tí ó jọni lójú.
Ọgbọ́n yóo parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ninu,
ìmọ̀ràn yóo sì parẹ́ mọ́ àwọn ọ̀mọ̀ràn níkùn.”
Ìrètí Ọjọ́ Ọ̀la
15Àwọn tí wọ́n fi èrò wọn pamọ́ fún OLUWA gbé;
àwọn tí iṣẹ́ wọn jẹ́ iṣẹ́ òkùnkùn,
tí ń wí pé, “Ta ló rí wa?
Ta ló mọ̀ wá?”
16Ẹ dorí gbogbo nǹkan kodò.#Ais 45:9; Sir 33:13; Rom 9:20
Ṣé eniyan lè sọ amọ̀kòkò di amọ̀?
Kí nǹkan tí eniyan ṣe, wí nípa ẹni tí ó ṣe é pé:
“Kìí ṣe òun ló ṣe mí.”
Tabi kí nǹkan tí eniyan dá sọ nípa ẹni tí ó dá a pé:
“Kò ní ìmọ̀.”
17Ṣebí díẹ̀ ṣínún ló kù
tí a óo sọ Lẹbanoni di ọgbà igi eléso
a óo sì máa pe ọgbà igi eléso náà ní igbó.
18Ní ọjọ́ náà, odi yóo gbọ́ ohun tí a kọ sinu ìwé,
ojú afọ́jú yóo ríran, ninu òkùnkùn biribiri rẹ̀.
19Àwọn onírẹ̀lẹ̀ yóo tún láyọ̀ láti ọ̀dọ̀ OLUWA.
Àwọn aláìní yóo máa yọ̀ ninu Ẹni Mímọ́ Israẹli
20nítorí pé àwọn aláìláàánú yóo di asán,
àwọn apẹ̀gàn yóo di òfo;
àwọn tí ń wá ọ̀nà láti ṣe ibi yóo parun;
21àwọn tí ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu sọ eniyan di ẹlẹ́ṣẹ̀,
tí ń dẹ tàkúté sílẹ̀ fún ẹni tí ń tọ́ni sọ́nà,
tí wọ́n sì ń fi àbòsí tí kò nídìí ti olódodo sí apá kan.
22Nítorí náà, OLUWA tí ó ra Abrahamu pada sọ nípa ilé Jakọbu pé,
“Ojú kò ní ti Jakọbu mọ́
bẹ́ẹ̀ ni ojú rẹ̀ kò ní rẹ̀wẹ̀sì mọ́.
23Nítorí nígbà tí ó bá rí àwọn ọmọ rẹ̀,
tíí ṣe iṣẹ́ ọwọ́ mi láàrin wọn,
wọn óo fi ọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.
Wọn óo bọ̀wọ̀ fún Ẹni Mímọ́ Jakọbu;
wọn óo sì bẹ̀rù Ọlọrun Israẹli.
24Àwọn tí ó ti ṣìnà ninu ẹ̀mí yóo ní òye;
àwọn tí ń kùn yóo sì gba ẹ̀kọ́.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 29: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀