Wọ́n ń sọ pé, “Ta ni yóo kọ́ lọ́gbọ́n? Ta sì ni yóo jíṣẹ́ náà fún? Ṣé àwọn tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọyàn lẹ́nu wọn, àbí àwọn tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ já lẹ́nu ọmú? Nítorí pé gbogbo rẹ̀ tòfin-tòfin ni, èyí òfin, tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún.” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àjèjì tí èdè wọn yàtọ̀ ni OLUWA yóo lò láti bá àwọn eniyan wọnyi sọ̀rọ̀. Àwọn tí ó ti wí fún pé: Ìsinmi nìyí, ẹ fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní ìsinmi; ìtura nìyí. Sibẹsibẹ wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. Nítorí náà ọ̀rọ̀ OLUWA sí wọn yóo jẹ́ tòfin-tòfin, èyí òfin tọ̀hún ìlànà. Díẹ̀ níhìn-ín, díẹ̀ lọ́hùn-ún, kí wọ́n baà lè lọ ṣubú sẹ́yìn kí wọ́n sì fọ́ wẹ́wẹ́; kí á lè dẹ tàkúté sílẹ̀ fún wọn, kí ọwọ́ lè tẹ̀ wọ́n.
Kà AISAYA 28
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: AISAYA 28:9-13
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò