HOSIA 1:1-11

HOSIA 1:1-11 YCE

Ọ̀rọ̀ tí OLUWA sọ fún Hosia, ọmọ Beeri nìyí, ní àkókò tí Usaya ati Jotamu, ati Ahasi, ati Hesekaya jọba ní ilẹ̀ Juda; tí Jeroboamu, ọmọ Joaṣi, sì jọba ní ilẹ̀ Israẹli. Nígbà tí Ọlọrun kọ́kọ́ bá Israẹli sọ̀rọ̀ láti ẹnu Hosia, Ọlọrun ní, “Lọ fẹ́ obinrin alágbèrè kan, kí o sì bí àwọn ọmọ alágbèrè; nítorí pé àwọn eniyan mi ti ṣe àgbèrè pupọ nípa pé, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀.” Hosia bá lọ fẹ́ iyawo kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gomeri, ọmọ Dibulaimu. Gomeri lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan fún un. OLUWA sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní Jesireeli; nítorí láìpẹ́ yìí ni n óo jẹ ìdílé Jehu níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ìpànìyàn tí ó dá ní Jesireeli, n óo sì fi òpin sí ìjọba Israẹli. Ní ọjọ́ náà, n óo run àwọn ọmọ ogun Israẹli ní àfonífojì Jesireeli.” Gomeri tún lóyún, ó sì bí ọmọbinrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé, “Sọ ọmọ náà ní, ‘Kò sí Àánú’; nítorí n kò ní ṣàánú àwọn eniyan Israẹli mọ́, n kò sì ní dáríjì wọ́n mọ́, ṣugbọn n óo fẹ́ràn ilé Juda, n óo sì ṣàánú wọn, èmi OLUWA Ọlọrun wọn yóo gbà wọ́n là, láìlo ọfà ati ọrun, idà tabi ogun, tabi ẹṣin ati àwọn ẹlẹ́ṣin.” Lẹ́yìn tí Gomeri gba ọmú lẹ́nu ‘Kò sí Àánú’ ó tún lóyún, ó sì bí ọmọkunrin kan. OLUWA tún sọ fún Hosia pé: “Sọ ọmọ náà ní ‘Kì í ṣe Eniyan Mi’, nítorí pé ẹ̀yin ọmọ Israẹli kì í ṣe eniyan mi, èmi náà kì í sì í ṣe Ọlọrun yín.” Àwọn ọmọ Israẹli yóo pọ̀ sí i bí iyanrìn etí òkun tí kò ṣe é wọ̀n, tí kò sì ṣe é kà. Níbi tí a ti sọ fún wọn pé, “Kì í ṣe eniyan mi”, níbẹ̀ ni a óo ti pè wọ́n ní, “ọmọ Ọlọrun Alààyè.” A óo kó àwọn eniyan Israẹli ati ti Juda papọ̀, wọn óo yan olórí kanṣoṣo fún ara wọn; wọn óo sì máa ti ibẹ̀ jáde wá. Dájúdájú, ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ Jesireeli yóo jẹ́.