HEBERU 5:7-9

HEBERU 5:7-9 YCE

Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ. Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́.