Bẹ́ẹ̀ gan-an ni, Kristi náà kò yan ògo yìí fúnrarẹ̀, láti jẹ́ olórí alufaa. Ọlọrun ni ó yàn án. Ọlọrun ni ó sọ fún un pé, “Ìwọ ni Ọmọ mi, lónìí ni mo bí ọ.” Bẹ́ẹ̀ náà ni ó sọ ní ibòmíràn pé, “Alufaa ni ọ́ títí laelae gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki.” Ní ìgbà ayé Jesu, pẹlu igbe ńlá ati ẹkún, ó fi adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ siwaju ẹni tí ó lè gbà á lọ́wọ́ ikú. Nítorí pé ó bọ̀wọ̀ fún Ọlọrun, adura rẹ̀ gbà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọmọ ni, ó kọ́ láti gbọ́ràn nípa ìyà tí ó jẹ. Nígbà tí a ti ṣe é ní àṣepé, ó wá di orísun ìgbàlà tí kò lópin fún gbogbo àwọn tí wọ́n bá gbà á gbọ́. Òun ni Ọlọrun pè ní olórí alufaa gẹ́gẹ́ bíi ti Mẹlikisẹdẹki. A ní ọ̀rọ̀ pupọ láti sọ fun yín nípa Mẹlikisẹdẹki yìí. Ọ̀rọ̀ náà ṣòro láti túmọ̀ nígbà tí ọkàn yín ti le báyìí.
Kà HEBERU 5
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HEBERU 5:5-11
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò