Nítorí náà, ó yẹ kí á túbọ̀ ṣe akiyesi àwọn ohun tí à ń gbọ́, kí á má baà gbá wa lọ bí ìgbà tí odò gbá nǹkan lọ. Nítorí bí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu àwọn angẹli sọ bá fẹsẹ̀ múlẹ̀, tí gbogbo ìwà àìṣedéédé ati ìwà àìgbọràn bá gba ìbáwí tí ó tọ́ sí wọn, báwo ni a óo ti ṣe sá àsálà, tí a bá kọ etí-ikún sí ìgbàlà tí ó tóbi tó báyìí? Oluwa fúnrarẹ̀ ni ó kọ́kọ́ kéde ìgbàlà yìí ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn tí wọ́n gbọ́ ni wọ́n fún wa ní ìdánilójú pé bẹ́ẹ̀ ni ó rí. Ọlọrun pàápàá tún jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ náà nípa àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu ati oríṣìíríṣìí iṣẹ́ tí ó ju agbára ẹ̀dá lọ, tí ó ṣe nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó pín gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀.
Kà HEBERU 2
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HEBERU 2:1-4
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò