HEBERU 13:14-21

HEBERU 13:14-21 YCE

Nítorí a kò ní ìlú tí yóo wà títí níhìn-ín, ṣugbọn à ń retí èyí tí ó ń bọ̀! Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á máa rú ẹbọ ìsìn sí Ọlọrun nígbà gbogbo nípasẹ̀ Jesu. Èyí ni ohun tí ó yẹ gbogbo ẹni tí ó bá ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe rere, kí ẹ sì máa fún àwọn ẹlòmíràn ninu àwọn ohun ìní yín. Irú ẹbọ yìí ni inú Ọlọrun dùn sí. Kí ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn aṣiwaju yín lẹ́nu, kí ẹ máa tẹ̀lé ìlànà wọn. Nítorí wọ́n ń ṣe akitiyan láìṣe àárẹ̀ láti tọ́jú yín, pẹlu ọkàn pé wọn yóo jíyìn iṣẹ́ wọn fún Ọlọrun. Ẹ mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ayọ̀ fún wọn, ẹ má jẹ́ kí ó jẹ́ ìrora. Bí ẹ bá mú kí iṣẹ́ wọn jẹ́ ìrora fún wọn, kò ní ṣe yín ní anfaani. Ẹ máa gbadura fún wa. Ó dá wa lójú pé ọkàn wa mọ́. Ohun tí ó dára ni a fẹ́ máa ṣe nígbà gbogbo. Nítorí náà mo tún bẹ̀ yín gidigidi pé kí ẹ máa gbadura fún wa, kí wọ́n baà lè dá mi sílẹ̀ kíákíá láti wá sọ́dọ̀ yín. Kí Ọlọrun alaafia, ẹni tí ó jí Jesu Oluwa wa dìde ninu òkú, Jesu, Olú olùṣọ́-aguntan, ẹni tí ó kú, kí ó baà lè fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ṣe èdìdì majẹmu ayérayé, kí ó mu yín pé ninu gbogbo ohun rere kí ẹ lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí ó lè máa ṣe ohun tí ó wù ú ninu yín nípasẹ̀ Jesu Kristi ẹni tí ògo wà fún lae ati laelae. Amin.