HEBERU 13:1-8

HEBERU 13:1-8 YCE

Àwọn onigbagbọ níláti fẹ́ràn ara wọn. Ẹ má gbàgbé láti máa ṣe àlejò nítorí nípa àlejò ṣíṣe àwọn ẹlòmíràn ti ṣe àwọn angẹli lálejò láìmọ̀ pé angẹli ni wọ́n. Ẹ ranti àwọn tí wọ́n wà lẹ́wọ̀n, kí ẹ ṣe bí ẹni pé ẹ̀yin náà wà lẹ́wọ̀n pẹlu wọn. Ẹ tún ranti àwọn tí à ń ni lára pẹlu, nítorí pé inú ayé ni ẹ wà sibẹ, irú nǹkan wọnyi lè ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀yin náà. Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè. Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!” Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, a lè fi ìgboyà sọ pé, “Oluwa ni olùrànlọ́wọ́ mi, ẹ̀rù kò ní bà mí. Ohun yòówù tí eniyan lè ṣe sí mi.” Ẹ ranti àwọn aṣiwaju yín, àwọn tí wọ́n mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun wá fun yín. Ẹ ronú nípa iṣẹ́ wọn ati bí wọ́n ṣe kú. Kí ẹ ṣe àfarawé igbagbọ wọn. Bákan náà ni Jesu Kristi wà lánàá, lónìí ati títí lae.