HEBERU 12:14-15

HEBERU 12:14-15 YCE

Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.