Níwọ̀n ìgbà tí a ní àwọn tí wọn ń jẹ́rìí sí agbára igbagbọ, tí wọ́n yí wa ká bí awọsanma báyìí, ẹ jẹ́ kí á pa gbogbo ohun ìdíwọ́ tì sápá kan, ati àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí ó rọrùn láti jẹ́ kí wọ́n dì mọ́ wa. Kí á fi ìfaradà sá iré ìje tí ó wà níwájú wa. Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun. Ẹ ro ti irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fọkàn rán àtakò àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, kí ọkàn yín má baà rẹ̀wẹ̀sì. Ninu ìjàkadì yín ẹ kò ì tíì tako ẹ̀ṣẹ̀ dé ojú ikú. Ẹ ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú inú Ìwé Mímọ́ níbi tí ó ti pè yín ní ọmọ, nígbà tí ó sọ pé, Ọmọ mi, má ṣe ka ìtọ́sọ́nà Oluwa sí nǹkan yẹpẹrẹ má sì jẹ́ kí ọkàn rẹ rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ó bá ń bá ọ wí. Nítorí ẹni tí Oluwa bá fẹ́ràn ni ó ń tọ́ sọ́nà, ẹni tí ó bá gbà bí ọmọ, ni ó ń nà ní pàṣán. Ẹ níláti faradà á bí ìtọ́sọ́nà. Ọlọrun mú yín bí ọmọ ni. Nítorí ọmọ wo ni ó wà tí baba rẹ̀ kò ní tọ́ sọ́nà? Bí ẹ kò bá ní irú ìtọ́sọ́nà tí gbogbo ọmọ máa ń ní, á jẹ́ pé ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í ṣe ọmọ tòótọ́. Ṣebí a ní àwọn baba tí wọ́n bí wa, tí wọn ń tọ́ wa sọ́nà, tí a sì ń bu ọlá fún wọn. Báwo ni ó wá yẹ kí á bọ̀wọ̀ fún Baba wa nípa ti ẹ̀mí tó, kí á sì ní ìyè? Fún ìgbà díẹ̀ ni àwọn baba wa nípa ti ara fi ń tọ́ wa, bí ó bá ti dára lójú wọn. Ṣugbọn Baba wa nípa ti ẹ̀mí ń tọ́ wa fún ire wa, kí á lè bá a pín ninu ìwà mímọ́ rẹ̀. Ní àkókò tí a bá ń sọ fún eniyan pé: má ṣe èyí, má ṣe tọ̀hún, kì í dùn mọ́ ẹni tí à ń tọ́. Pẹlu ìnira ni. Ṣugbọn ní ìgbẹ̀yìn a máa so èso alaafia ti ìgbé-ayé òdodo fún àwọn tí a bá ti tọ́ sọ́nà. Nítorí náà ẹ gbé ọwọ́ yín tí kò lágbára sókè, ẹ mú kí eékún yín tí ń gbọ̀n di alágbára; ẹ ṣe ọ̀nà títọ́ fún ara yín láti máa rìn, kí ẹsẹ̀ tí ó bá ti rọ má baà yẹ̀, ṣugbọn kí ó lè mókun. Ẹ máa lépa alaafia lọ́dọ̀ gbogbo eniyan pẹlu ìwà mímọ́. Láìṣe bẹ́ẹ̀ kò sí ẹni tí yóo rí Oluwa. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni ninu yín má fà sẹ́yìn kúrò ninu oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe dàbí igi kíkorò, tí yóo dàgbà tán tí yóo wá fi ìkorò tirẹ̀ kó ìdààmú bá ọpọlọpọ ninu yín.
Kà HEBERU 12
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: HEBERU 12:1-15
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò