Jakọbu ń gbé ilẹ̀ Kenaani, níbi tí àwọn baba rẹ̀ ti ṣe àtìpó. Àkọsílẹ̀ ìran Jakọbu nìyí: Josẹfu jẹ́ ọmọ ọdún mẹtadinlogun ó sì ń bá àwọn arakunrin rẹ̀ tọ́jú agbo ẹran ó wà lọ́dọ̀ àwọn ọmọ Biliha ati àwọn ọmọ Silipa, àwọn aya baba rẹ̀. Josẹfu a sì máa sọ gbogbo àṣìṣe àwọn arakunrin rẹ̀ fún baba wọn.
Israẹli fẹ́ràn Josẹfu ju gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù lọ, nítorí pé ó ti di arúgbó kí ó tó bí i, nítorí náà ó dá ẹ̀wù aláràbarà kan fún un. Nígbà tí àwọn arakunrin rẹ̀ yòókù rí i pé baba wọn fẹ́ràn Josẹfu ju àwọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọn kì í sì fi sùúrù bá a sọ̀rọ̀.
Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lá àlá kan, ó bá rọ́ àlá náà fún àwọn arakunrin rẹ̀, àlá yìí sì jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. Ó sọ fún wọn pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ gbọ́ àlá kan tí mo lá. Èmi pẹlu yín, a wà ní oko ní ọjọ́ kan, à ń di ìtí ọkà, mo rí i tí ìtí ọkà tèmi wà lóòró, ó dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì yí i ká, wọ́n ń foríbalẹ̀ fún un.”
Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bi í pé, “Ṣé o rò pé ìwọ ni yóo jọba lórí wa ni? Tabi o óo máa pàṣẹ lé wa lórí?” Wọ́n sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i nítorí àlá tí ó lá ati nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ó tún lá àlá mìíràn, ó sì tún rọ́ ọ fún àwọn arakunrin rẹ̀, ó ní, “Ẹ gbọ́, mo mà tún lá àlá mìíràn! Mo rí oòrùn, ati òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ mọkanla ní ojú àlá, gbogbo wọn foríbalẹ̀ fún mi.”
Nígbà tí ó rọ́ àlá náà fún baba rẹ̀ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Baba rẹ̀ bá a wí, ó ní, “Irú àlá rándanràndan wo ni ò ń lá wọnyi? Ṣé èmi, ati ìyá rẹ, ati àwọn arakunrin rẹ yóo wá foríbalẹ̀ fún ọ ni?” Àwọn arakunrin rẹ̀ bá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara rẹ̀, ṣugbọn baba rẹ̀ kò gbàgbé ọ̀rọ̀ náà, ó ń rò ó ní ọkàn rẹ̀.