JẸNẸSISI 34:1-12

JẸNẸSISI 34:1-12 YCE

Ní ọjọ́ kan, Dina, ọmọbinrin tí Lea bí fún Jakọbu jáde lọ kí àwọn obinrin kan ní ìlú Ṣekemu. Nígbà tí Ṣekemu ọmọ Hamori, ará Hifi, tíí ṣe ọmọ ọba ìlú náà rí i, ó fi ipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀ tipátipá. Ọkàn rẹ̀ fà sí Dina ọmọ Jakọbu, ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fún un. Ṣekemu bá lọ sọ fún Hamori, baba rẹ̀, pé kí ó fẹ́ ọmọbinrin náà fún òun. Jakọbu ti gbọ́ pé ó ti ba Dina, ọmọ rẹ̀ jẹ́, ṣugbọn àwọn ọmọ rẹ̀ wà pẹlu àwọn ẹran ninu pápá, Jakọbu kò sọ nǹkankan títí tí wọ́n fi dé. Hamori baba Ṣekemu tọ Jakọbu wá láti bá a sọ̀rọ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ Jakọbu pada dé sílé, tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, inú bí wọn gidigidi nítorí bíbá tí Ṣekemu bá Dina lòpọ̀ pẹlu ipá yìí jẹ́ ìwà àbùkù gbáà ní Israẹli, irú ìwà bẹ́ẹ̀ kò tọ́ sí ẹnikẹ́ni láti hù. Ṣugbọn Hamori bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní, “Ọkàn Ṣekemu, ọmọ mi, fà sí arabinrin yín, ẹ jọ̀wọ́, ẹ fún un kí ó fi ṣe aya. Ẹ jẹ́ kí á jọ máa fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ ara wa, ẹ máa fi àwọn ọmọbinrin yín fún wa, kí àwa náà máa fi àwọn ọmọbinrin wa fún yín. A óo jọ máa gbé pọ̀, ibi tí ó bá wù yín ni ẹ lè gbé, ibi tí ẹ bá fẹ́ ni ẹ ti lè ṣòwò, tí ẹ sì lè ní ohun ìní.” Ṣekemu tún wí fún baba ati àwọn arakunrin omidan náà pé, “Ẹ jọ̀wọ́, ẹ yọ́nú sí mi, ohunkohun tí ẹ bá ní kí n san, n óo san án. Iyekíye tí ó bá wù yín ni kí ẹ bèèrè fún owó orí iyawo, n óo san án, ẹ ṣá ti fi omidan náà fún mi.”