Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, wọ́n gbúròó OLUWA Ọlọrun tí ń rìn ninu ọgbà. Wọ́n bá sá pamọ́ sí ààrin àwọn igi ọgbà. Ṣugbọn OLUWA Ọlọrun pe ọkunrin náà, ó bi í pé, “Níbo ni o wà?”
Ó dá Ọlọrun lóhùn, ó ní, “Nígbà tí mo gbúròó rẹ ninu ọgbà, ẹ̀rù bà mí, mo bá farapamọ́ nítorí pé ìhòòhò ni mo wà.”
Ọlọrun bi í pé, “Ta ló sọ fún ọ pé ìhòòhò ni o wà? Àbí o ti jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ?”
Ọkunrin náà dáhùn, ó ní, “Obinrin tí o fi tì mí ni ó fún mi ninu èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”
OLUWA Ọlọrun bi obinrin náà pé, “Irú kí ni o dánwò yìí?” Obinrin náà dáhùn, ó ní, “Ejò ni ó tàn mí tí mo fi jẹ ẹ́.”
OLUWA Ọlọrun bá sọ fún ejò náà pé,
“Nítorí ohun tí o ṣe yìí,
o di ẹni ìfibú jùlọ láàrin gbogbo àwọn ẹran ọ̀sìn ati àwọn ẹranko.
Àyà rẹ ni o óo máa fi wọ́ káàkiri,
erùpẹ̀ ni o óo sì máa jẹ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
N óo dá ọ̀tá sí ààrin ìwọ ati obinrin náà,
ati sí ààrin atọmọdọmọ rẹ ati atọmọdọmọ rẹ̀.
Wọn óo máa fọ́ ọ lórí,
ìwọ náà óo sì máa bù wọ́n ní gìgísẹ̀ jẹ.”
Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé,
“N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún,
ninu ìrora ni o óo máa bímọ.
Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí,
òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”
Ó sọ fún Adamu, pé,
“Nítorí pé o gba ohun tí aya rẹ wí fún ọ,
o sì jẹ ninu èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé o kò gbọdọ̀ jẹ,
mo fi ilẹ̀ gégùn-ún títí lae nítorí rẹ.
Pẹlu ìnira ni o óo máa mú oúnjẹ jáde láti inú ilẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.
Ẹ̀gún ati òṣùṣú ni ilẹ̀ yóo máa hù jáde fún ọ,
ewéko ni o óo sì máa jẹ.
Iṣẹ́ àṣelàágùn ni o óo máa ṣe, kí o tó rí oúnjẹ jẹ,
títí tí o óo fi pada sí ilẹ̀,
nítorí inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá.
Erùpẹ̀ ni ọ́,
o óo sì pada di erùpẹ̀.”
Adamu sọ iyawo rẹ̀ ní Efa, nítorí pé òun ni ìyá gbogbo eniyan. OLUWA Ọlọrun fi awọ ẹranko rán aṣọ fún Adamu ati iyawo rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.
Lẹ́yìn náà, OLUWA Ọlọrun wí pé, “Nisinsinyii tí ọkunrin náà ti dàbí wa, tí ó sì ti mọ ire yàtọ̀ sí ibi, kí ó má lọ mú ninu èso igi ìyè, kí ó jẹ ẹ́, kí ó sì wà láàyè títí lae.” Nítorí náà OLUWA Ọlọrun lé e jáde kúrò ninu ọgbà Edẹni, kí ó lọ máa ro ilẹ̀, ninu èyí tí Ọlọrun ti mú un jáde. Ó lé e jáde, ó sì fi Kerubu kan sí ìhà ìlà oòrùn ọgbà náà láti máa ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè náà, pẹlu idà oníná tí ń jò bùlà bùlà, tí ó sì ń yí síhìn-ín sọ́hùn-ún.