Ní àkókò kan, ìyàn ńlá kan mú ní ilẹ̀ náà, yàtọ̀ sí ìyàn tí ó mú ní ìgbà Abrahamu. Isaaki bá tọ Abimeleki ọba àwọn ará Filistini lọ ní Gerari. Kí ó tó lọ sí Gerari, Ọlọrun farahàn án, ó sì kìlọ̀ fún un pé kò gbọdọ̀ lọ sí Ijipti, kí ó máa gbé ilẹ̀ tí òun sọ fún un. Ọlọrun ní, “Máa gbé ilẹ̀ yìí, n óo wà pẹlu rẹ, n óo sì bukun ọ, nítorí ìwọ ati àwọn ọmọ rẹ ni n óo fún ní ilẹ̀ wọnyi, n óo sì mú ìlérí mi fún Abrahamu, baba rẹ ṣẹ. N óo sọ àwọn ọmọ rẹ di pupọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ wọnyi. Nípasẹ̀ wọn ni n óo bukun gbogbo orílẹ̀-èdè ayé, nítorí pé Abrahamu gbọ́ràn sí mi lẹ́nu, ó sì pa gbogbo òfin ati ìlànà mi mọ́ patapata.”
Isaaki bá ń gbé Gerari. Nígbà tí àwọn ará ìlú náà bèèrè bí Rebeka ti jẹ́ sí i, ó sọ fún wọn pé arabinrin òun ni. Ẹ̀rù bà á láti jẹ́wọ́ fún wọn pé iyawo òun ni, nítorí ó rò pé àwọn ará ìlú náà lè pa òun nítorí pe Rebeka jẹ́ arẹwà obinrin. Ní ọjọ́ kan, lẹ́yìn tí Isaaki ti ń gbé ìlú náà fún ìgbà pípẹ́, Abimeleki, ọba àwọn ará ìlú Filistia yọjú lójú fèrèsé ààfin rẹ̀, ó rí i tí Isaaki ati Rebeka ń tage. Abimeleki bá pe Isaaki, ó wí pé, “Àṣé iyawo rẹ ni Rebeka! Kí ni ìdí tí o fi pè é ní arabinrin rẹ fún wa?” Isaaki bá dáhùn pé, “Mo rò pé wọ́n lè pa mí nítorí rẹ̀ ni.”
Abimeleki bá dá a lóhùn pé, “Irú kí ni o dánwò sí wa yìí? Ǹjẹ́ bí ọ̀kan ninu àwọn eniyan wọnyi bá ti bá aya rẹ lòpọ̀ ńkọ́? O ò bá mú ẹ̀bi wá sórí wa.” Nítorí náà Abimeleki kìlọ̀ fún gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan ọkunrin yìí tabi aya rẹ̀, pípa ni wọn yóo pa á.”
Isaaki dá oko ní ilẹ̀ náà, láàrin ọdún kan ṣoṣo ó rí ìkórè ìlọ́po lọ́nà ọgọrun-un (100) ohun tí ó gbìn nítorí OLUWA bukun un. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní àníkún títí ó fi di ọlọ́rọ̀. Ó ní ọpọlọpọ agbo aguntan ati agbo mààlúù, pẹlu ọpọlọpọ iranṣẹ tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn ará Filistia bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀. Gbogbo kànga tí àwọn iranṣẹ Abrahamu baba rẹ̀ gbẹ́ ní àkókò tí Abrahamu wà láyé ni àwọn ará Filistia rọ́ yẹ̀ẹ̀pẹ̀ dí.
Abimeleki bá wí fún Isaaki pé, “Kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé o ti lágbára jù wá lọ.”