JẸNẸSISI 25:29-33

JẸNẸSISI 25:29-33 YCE

Ní ọjọ́ kan, bí Jakọbu ti ń se ẹ̀bẹ lọ́wọ́ ni Esau ti oko ọdẹ dé, ebi sì ti fẹ́rẹ̀ pa á kú. Esau sọ fún Jakọbu pé, “Jọ̀wọ́ fún mi jẹ ninu ẹ̀bẹ tí ó pupa yìí nítorí pé ebi ń pa mí kú lọ.” (Nítorí ọ̀rọ̀ yìí ni wọ́n ṣe ń pè é ní Edomu.) Jakọbu bá dáhùn pé, “Kọ́kọ́ gbé ipò àgbà rẹ fún mi ná.” Esau dá a lóhùn, ó ní, “Ebi ń pa mí kú lọ báyìí, ò ń sọ̀rọ̀ ipò àgbà, kí ni ipò àgbà fẹ́ dà fún mi?” Jakọbu dáhùn pé, “Kọ́kọ́ búra fún mi ná.” Esau bá búra fún Jakọbu, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ gbé ipò àgbà fún un.