JẸNẸSISI 2:1-4

JẸNẸSISI 2:1-4 YCE

Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe parí dídá ọ̀run ati ayé, ati gbogbo ohun tí ó wà ninu wọn. Ní ọjọ́ keje, Ọlọrun parí iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe, ó sì sinmi ní ọjọ́ náà. Ó súre fún ọjọ́ keje yìí, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ọjọ́ náà ni ó sinmi ninu gbogbo iṣẹ́ ìṣẹ̀dá tí ó ti ń ṣe bọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni Ọlọrun ṣe dá ọ̀run ati ayé. Nígbà tí OLUWA Ọlọrun dá ọ̀run ati ayé