ISIKIẸLI 31

31
A Fi Ijipti Wé Igi Kedari
1Ní ọjọ́ kinni, oṣù kẹta, ọdún kọkanla tí a ti wà ní ìgbèkùn, OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 2“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún Farao, ọba Ijipti, pẹlu ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ pé,
Ta ni ó lágbára tó ọ?
3Wò ó! Mo fi ọ́ wé igi kedari Lẹbanoni,
àwọn ẹ̀ka rẹ̀ lẹ́wà,
wọ́n sì ní ìbòòji ó ga fíofío,
orí rẹ̀ sì kan ìkùukùu lójú ọ̀run.
4Omi mú kí ó dàgbà,
ibú omi sì mú kí ó ga.
Ó ń mú kí àwọn odò rẹ̀ ṣàn yí ibi tí a gbìn ín sí ká.
Ó ń mú kí odò rẹ̀ ṣàn lọ síbi gbogbo igi igbó.
5Nítorí náà, ó ga sókè fíofío, ju gbogbo igi inú igbó lọ.
Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ tóbi, wọ́n sì gùn,
nítorí ọpọlọpọ omi tí ó ń rí.
6Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run, pa ìtẹ́ sára àwọn ẹ̀ka rẹ̀.
Lábẹ́ rẹ̀ ni gbogbo ẹranko inú igbó ń bímọ sí.
Gbogbo orílẹ̀-èdè ńláńlá sì fi ìbòòji abẹ́ rẹ̀ ṣe ibùgbé.
7Ó tóbi, ó lọ́lá ẹ̀ka rẹ̀ sì lẹ́wà
nítorí pé gbòǹgbò rẹ̀ wọ ilẹ̀ lọ,
ó sì kan ọpọlọpọ omi nísàlẹ̀ ilẹ̀.
8Igi kedari tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun kò lè farawé e.
Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀ka igi firi kò sì tó ẹ̀ka rẹ̀.
Ẹ̀ka igi kankan kò dàbí ẹ̀ka rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni kò sí igikígi ninu ọgbà Ọlọrun tí ó lẹ́wà bíi rẹ̀.
9Mo dá a ní arẹwà, pẹlu ẹ̀ka tí ó pọ̀.
Gbogbo igi ọgbà Edẹni,
tí ó wà ninu ọgbà Ọlọrun sì ń jowú rẹ̀. #Jẹn 2:9
10“Nítorí pé ó ga sókè fíofío, góńgó orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu lójú ọ̀run, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìgbéraga nítorí gíga rẹ̀. 11N óo fi lé ẹni tí ó lágbára jù láàrin àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, yóo sì ṣe é fún un gẹ́gẹ́ bí ìwà ìkà rẹ̀. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo lé e jáde. 12Àwọn àjèjì láti inú orílẹ̀-èdè, tí ó burú jùlọ, yóo gé e lulẹ̀, wọn yóo sì fi í sílẹ̀. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo bọ́ sílẹ̀ lórí àwọn òkè ati ní àwọn àfonífojì, igi rẹ̀ yóo sì wà nílẹ̀ káàkiri ní gbogbo ipadò ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè yóo kúrò lábẹ́ òjìji rẹ̀, wọn yóo sì fi sílẹ̀. 13Gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run yóo kọ́lé sórí ìtì igi rẹ̀ tí ó wó lulẹ̀. Gbogbo ẹranko inú igbó yóo tẹ àwọn ẹ̀ka rẹ̀ mọ́lẹ̀. 14Gbogbo èyí yóo ṣẹlẹ̀ kí igi mìíràn tí ó bá wà lẹ́bàá omi náà má baà ga fíofío mọ́, tabi kí orí rẹ̀ wọ inú ìkùukùu ní ojú ọ̀run. Kò sì ní sí igi tí ń fa omi, tí yóo ga tó ọ; nítorí gbogbo wọn ni wọn óo kú, tí wọn óo sì lọ sí ìsàlẹ̀ ọ̀gbun ilẹ̀ bí àwọn alààyè eniyan tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú.”
15OLUWA Ọlọrun ní: “Nígbà tí ó bá wọ isà òkú ọ̀gbun ilẹ̀ pàápàá, n óo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, n óo sé àwọn odò n óo sì ti orísun omi ìsàlẹ̀ ilẹ̀ nítorí rẹ̀, òkùnkùn óo bo Lẹbanoni, gbogbo igi inú igbó yóo gbẹ nítorí rẹ̀. 16Ìró wíwó rẹ̀ yóo mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì. Nígbà tí mo bá wó o lulẹ̀ tí mo bá sọ ọ́ sinu isà òkú pẹlu àwọn tí wọ́n ti lọ sí ipò òkú; gbogbo àwọn igi Edẹni, ati àwọn igi tí wọ́n dára jù ní Lẹbanoni, gbogbo àwọn igi tí ń rí omi mu lábẹ́ ilẹ̀ ni ara yóo tù. 17Àwọn náà yóo lọ sí ipò òkú pẹlu rẹ̀, sọ́dọ̀ àwọn tí wọ́n fi idà pa; àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ń gbé abẹ́ òjìji rẹ̀ yóo sì parun.
18“Ògo ati títóbi ta ni a lè fi wé tìrẹ láàrin àwọn igi tí ó wà ní Edẹni? Ṣugbọn a óo gé ọ lulẹ̀ pẹlu àwọn igi ọgbà Edẹni, a óo sì wọ́ ọ sọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀. O óo wà nílẹ̀ láàrin àwọn aláìkọlà,#31:18 Àwọn aláìkọlà ni àwọn tí kì í ṣe Juu, tí kò sì gba Ọlọrun gbọ́. pẹlu àwọn tí a fi idà pa. Farao ati ogunlọ́gọ̀ àwọn eniyan rẹ̀ ni mò ń sọ nípa wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ISIKIẸLI 31: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀