ISIKIẸLI 22
22
Ìwà Ibi Jerusalẹmu
1OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2“Ìwọ ọmọ eniyan, ṣé o óo dájọ́, ṣé o óo dájọ́ ìlú tí ó kún fún ìpànìyàn yìí? Sọ gbogbo ìwà ìríra rẹ̀ fún un. 3Sọ fún un pé èmi OLUWA Ọlọrun ní, ìwọ ìlú tí wọ́n ti ń paniyan ní ìpakúpa kí àkókò ìjìyà rẹ̀ lè tètè dé, ìlú tí ń fi oriṣa ba ara rẹ̀ jẹ́! 4A ti dá ọ lẹ́bi nítorí àwọn eniyan tí o pa, o sì ti di aláìmọ́ nítorí àwọn ère tí o gbẹ́. O ti mú kí ọjọ́ ìjìyà rẹ súnmọ́ tòsí, ọdún tí a dá fún ọ sì pé tán. Nítorí náà, mo ti sọ ọ́ di ẹni ẹ̀gàn láàrin àwọn eniyan, ati ẹni yẹ̀yẹ́ lójú gbogbo orílẹ̀-èdè. 5Àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n súnmọ́ ọ ati àwọn tí wọ́n jìnnà sí ọ yóo máa fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, ìwọ tí o kò níyì, tí o kún fún ìdàrúdàpọ̀. 6Wo àwọn olórí ní ilẹ̀ Israẹli tí wọ́n wà ninu rẹ, olukuluku ti pinnu láti máa lo agbára rẹ̀ láti máa paniyan. 7Àwọn ọmọ kò náání baba ati ìyá wọn ninu rẹ; wọ́n sì ń ni àwọn àjèjì ninu rẹ lára; wọ́n sì ń fìyà jẹ àwọn aláìníbaba ati opó. 8O kò bìkítà fún àwọn ohun mímọ́ mi, o sì ti ba ọjọ́ ìsinmi mi jẹ́. 9Àwọn eniyan inú rẹ ń parọ́ láti paniyan. Wọ́n ń jẹbọ kiri lórí àwọn òkè ńláńlá, wọ́n sì ń ṣe ohun ìtìjú. 10Àwọn mìíràn ń bá aya baba wọn lòpọ̀, wọ́n sì ń fi ipá bá obinrin lòpọ̀ ní ìgbà tí ó ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀ lọ́wọ́. 11Ẹnìkínní ń bá aya ẹnìkejì rẹ̀ lòpọ̀; àwọn kan ń bá aya ọmọ wọn lòpọ̀; ẹ̀gbọ́n ń bá àbúrò rẹ̀ lòpọ̀, àwọn mìíràn sì ń bá ọbàkan wọn lòpọ̀ ninu rẹ, Jerusalẹmu. 12Wọ́n ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti paniyan láàrin ìlú, wọ́n ń gba owó èlé, ẹ̀ ń ní àníkún, ẹ sì ń fi ipá gba owó lọ́wọ́ aládùúgbò yín, ẹ ti gbàgbé mi, èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀. #a Eks 20:12; Diut 5:16; b Eks 22:21-22; Diut 24:17 #Lef 19:30; 26:2 #Lef 18:7-20 #Eks 23:8; Diut 16:19; Eks 22:25; Lef 25:36-37; Diut 23:19
13“Nítorí náà mo pàtẹ́wọ́ le yín lórí nítorí èrè aiṣootọ tí ẹ̀ ń jẹ ati eniyan tí ẹ̀ ń pa ninu ìlú. 14Ǹjẹ́ o lè ní ìgboyà ati agbára ní ọjọ́ tí n óo bá jẹ ọ́ níyà. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni n óo sì ṣe. 15N óo fọn yín káàkiri ààrin àwọn àjèjì; n óo tu yín ká sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, n óo fi òpin sí ìwà èérí tí ẹ̀ ń hù ní Jerusalẹmu. 16N óo di ẹni ìdọ̀tí lójú àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn nítorí rẹ, o óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA.”
Ọlọrun Ṣe Àtúnṣe
17OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 18“Ìwọ ọmọ eniyan; àwọn ọmọ Israẹli ti di ìdàrọ́ lójú mi. Wọ́n dàbí idẹ, páànù, irin, ati òjé tí ó wà ninu iná alágbẹ̀dẹ. Wọ́n dàbí ìdàrọ́ ara fadaka. 19Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní níwọ̀n ìgbà tí gbogbo yín ti di ìdàrọ́, n óo ko yín jọ sí ààrin Jerusalẹmu. 20Bí eniyan ṣe ń kó fadaka, idẹ, irin, òjé ati páànù pọ̀ sinu ìkòkò lórí iná alágbẹ̀dẹ, kí wọ́n lè yọ́, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu ati ìrúnú ko yín jọ n óo sì yọ yín. 21N óo ko yín jọ, n óo fẹ́ ìrúnú mi si yín lára bí iná, ẹ óo sì yọ́. 22Bí wọn tí ń yọ́ fadaka ninu iná alágbẹ̀dẹ, bẹ́ẹ̀ ni n óo fi ibinu yọ yín, ẹ óo sì mọ̀ pé èmi OLUWA ni mo bínú si yín.”
Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Olórí Israẹli
23OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní, 24“Ìwọ ọmọ eniyan, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé ilẹ̀ tí kò mọ́ ni ilẹ̀ wọn, ilẹ̀ tí òjò kò rọ̀ sí lákòókò ibinu èmi OLUWA. 25Àwọn olórí tí wọ́n wà nílùú dàbí kinniun tí ń bú, tí ó sì ń fa ẹran ya. Wọ́n ti jẹ àwọn eniyan run, wọ́n ń fi ipá já ohun ìní ati àwọn nǹkan olówó iyebíye gbà, wọ́n ti sọ ọpọlọpọ obinrin di opó nílùú. 26Àwọn alufaa rẹ̀ ti kọ òfin mi sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́. Wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrin àwọn nǹkan mímọ́ ati nǹkan àìmọ́; wọn kò sì kọ́ àwọn eniyan ní ìyàtọ̀ tí ó wà láàrin nǹkan mímọ́ ati àìmọ́. Wọn kò bìkítà fún ọjọ́ ìsinmi mi, mo sì ti di aláìmọ́ láàrin wọn. 27Àwọn olórí tí ó wà ninu wọn dàbí ìkookò tí ń fa ẹran ya, wọ́n ń pa eniyan, wọ́n sì ń run eniyan láti di olówó. 28Àwọn wolii wọn ń tàn wọ́n, wọ́n ń ríran irọ́, wọ́n ń woṣẹ́ èké. Wọ́n ń wí pé, OLUWA sọ báyìí, báyìí; bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò sọ nǹkankan. 29Àwọn eniyan ilẹ̀ náà ń fi ipá gba nǹkan-oní-nǹkan; wọ́n ń ni talaka ati aláìní lára, wọ́n sì ń fi ipá gba nǹkan lọ́wọ́ àwọn àlejò láì ṣe àtúnṣe. 30Mo wá ẹnìkan láàrin wọn tí ìbá tún odi náà mọ, kí ó sì dúró níbi tí odi ti ya níwájú mi láti bẹ̀bẹ̀ fún ilẹ̀ náà, kí n má baà pa á run, ṣugbọn n kò rí ẹnìkan. 31Nítorí náà, n óo bínú sí wọn; n óo fi ìrúnú pa wọ́n rẹ́, n óo sì gbẹ̀san ìwà wọn lára wọn. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” #Lef 10:10
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ISIKIẸLI 22: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010