Àwọn àgbààgbà Israẹli kan tọ̀ mí wá, wọ́n jókòó siwaju mi. OLUWA bá bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: “Ìwọ ọmọ eniyan, àwọn ọkunrin wọnyi kó oriṣa wọn lé ọkàn, wọ́n sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju wọn. Ṣé wọ́n rò pé n óo dá wọn lóhùn tí wọ́n bá wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ mi? “Nítorí náà, sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tí ó bá kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn tí ó gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ siwaju rẹ̀, tí ó wá tọ wolii wá, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ oriṣa rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe, kí n lè dá ọkàn àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n ṣáko kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí oriṣa wọn pada. “Nítorí náà, sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé èmi OLUWA Ọlọrun ní kí wọn ronupiwada, kí wọn pada lẹ́yìn àwọn oriṣa wọn, kí wọn yíjú kúrò lára àwọn nǹkan ìríra tí wọn ń bọ “Nítorí pé bí ẹnikẹ́ni ninu ẹ̀yin ọmọ Israẹli tabi ninu àwọn àlejò tí wọ́n wọ̀ ní ilẹ̀ Israẹli bá ya ara rẹ̀ kúrò lọ́dọ̀ mi, tí ó Kó oriṣa rẹ̀ lé ọkàn, tí ó sì gbé ẹrù ẹ̀ṣẹ̀ tí ń múni kọsẹ̀ ka iwájú rẹ̀, tí ó wá tọ wolii lọ láti wádìí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ ní orúkọ mi, èmi OLUWA fúnra mi ni n óo dá a lóhùn. N óo dójú lé olúwarẹ̀, n óo fi ṣe ẹni àríkọ́gbọ́n ati àmúpòwe. N óo pa á run láàrin àwọn eniyan mi; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.
Kà ISIKIẸLI 14
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ISIKIẸLI 14:1-8
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò