Lẹ́yìn náà, Mose ati Aaroni lọ sọ́dọ̀ Farao, wọ́n sọ fún un pé, “OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ pé, ‘Jẹ́ kí àwọn eniyan mi lọ, kí wọ́n lè lọ ṣe àjọ̀dún kan fún mi ninu aṣálẹ̀.’ ”
Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ta ni OLUWA yìí tí n óo fi fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí n sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ? N kò mọ OLUWA ọ̀hún, ati pé n kò tilẹ̀ lè gbà rárá pé kí àwọn ọmọ Israẹli lọ.”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ọlọrun àwọn Heberu ni ó farahàn wá; jọ̀wọ́, fún wa ní ààyè láti lọ sí aṣálẹ̀ ní ìwọ̀n ìrìn ọjọ́ mẹta, kí á lè lọ rúbọ sí OLUWA Ọlọrun wa, kí ó má baà fi àjàkálẹ̀ àrùn tabi ogun bá wa jà.”
Ṣugbọn ọba Ijipti dá wọn lóhùn pé, “Ìwọ Mose ati ìwọ Aaroni, kí ló dé tí ẹ fi kó àwọn eniyan wọnyi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ kó wọn pada kíákíá.” Farao fi kún un pé, “Ṣé ẹ̀yin náà rí i pé àwọn eniyan yìí pọ̀ pupọ ju àwọn ọmọ-ìbílẹ̀ ilẹ̀ yìí lọ, ẹ sì tún kó wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn?”
Ní ọjọ́ náà gan-an ni Farao pàṣẹ fún gbogbo àwọn ọ̀gá tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ fún àwọn eniyan wọnyi ní koríko láti fi ṣe bíríkì bí ẹ ti ṣe ń fún wọn tẹ́lẹ̀ mọ; ẹ jẹ́ kí wọn máa lọ kó koríko fúnra wọn. Iye bíríkì tí wọn ń ṣe tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín; nítorí pé nígbà tí iṣẹ́ kò ká wọn lára ni wọ́n ṣe ń rí ààyè pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí á lọ rúbọ sí Ọlọrun wa.’ Ẹ fi iṣẹ́ kún iṣẹ́ wọn. Nígbà tí iṣẹ́ bá wọ̀ wọ́n lọ́rùn gan-an, bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ ń parọ́ fún wọn, wọn kò ní fetí sí i.”
Àwọn tí wọn ń kó àwọn ọmọ Israẹli ṣiṣẹ́ bá jáde tọ̀ wọ́n lọ, wọ́n sọ fún wọn pé, “Ẹ gbọ́ bí Farao ti wí; ó ní òun kò ní fún yín ní koríko mọ́. Ó ní kí ẹ lọ máa wá koríko fúnra yín níbikíbi tí ẹ bá ti rí. Ṣugbọn iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò gbọdọ̀ dín!” Wọ́n bá fọ́n káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ijipti láti wá àgékù koríko. Àwọn tí wọn ń kó wọn ṣiṣẹ́ a máa fi ipá mú wọn pé, lojumọ, wọ́n gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí wọ́n máa ń mọ tẹ́lẹ̀, nígbà tí wọn kò tíì máa wá koríko fúnra wọn. Àwọn akóniṣiṣẹ́ Farao bẹ̀rẹ̀ sí na àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli. Wọn á máa bi wọ́n pé “Kí ló dé tí bíríkì tí ẹ mọ lónìí kò fi tó iye tí ó yẹ kí ẹ mọ?”
Àwọn tí wọ́n fi ṣe olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli bá ké tọ Farao lọ, wọ́n ní, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe báyìí sí àwa iranṣẹ rẹ? Ẹnikẹ́ni kò fún wa ní koríko, sibẹ wọ́n ní dandan, a gbọdọ̀ mọ iye bíríkì tí à ń mọ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń lù wá, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ará Ijipti gan-an ni wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà.”
Ṣugbọn Farao dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀lẹ ni yín, ẹ kò fẹ́ ṣiṣẹ́ ni ẹ fi ń sọ pé kí n jẹ́ kí ẹ lọ rúbọ sí OLUWA. Ẹ kúrò níwájú mi nisinsinyii, kí ẹ lọ máa ṣiṣẹ́ yín; kò sí ẹni tí yóo fún yín ní koríko, iye bíríkì tí ẹ̀ ń mọ tẹ́lẹ̀ kò sì gbọdọ̀ dín.” Àwọn tí wọ́n jẹ́ olórí láàrin àwọn ọmọ Israẹli rí i pé àwọn wà ninu ewu, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé iye bíríkì tí àwọn ń mọ lojumọ kò gbọdọ̀ dín rárá.
Bí wọ́n ti ń ti ọ̀dọ̀ Farao bọ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ Mose ati Aaroni tí wọ́n dúró dè wọ́n, wọ́n sì sọ fún wọn pé, “Ọlọrun ni yóo dájọ́ fún yín, ẹ̀yin tí ẹ sọ wá di ẹni ìríra níwájú Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ẹ sì ti yọ idà lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n fi pa wá.”