Igbe àwọn eniyan Israẹli ti gòkè tọ̀ mí wá, mo sì ti rí bí àwọn ará Ijipti ṣe ń ni wọ́n lára. Wá, n óo rán ọ sí Farao, kí o lè lọ kó àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Mose dá Ọlọrun lóhùn pé, “Ta ni mo jẹ́, tí n óo fi wá tọ Farao lọ pé mo fẹ́ kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti?” Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.” Mose tún bi Ọlọrun pé, “Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli, tí mo sì wí fún wọn pé, ‘Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ bí wọ́n bá wá bi mí pé ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n wí fún wọn?” Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ”
Kà ẸKISODU 3
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: ẸKISODU 3:9-14
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò