ẸKISODU 3:1-16

ẸKISODU 3:1-16 YCE

Ní ọjọ́ kan, Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, tíí ṣe alufaa ìlú Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ìhà ìwọ̀ oòrùn aṣálẹ̀, títí tí ó fi dé òkè Horebu ní Sinai, tíí ṣe òkè Ọlọrun. Angẹli OLUWA farahàn án ninu ahọ́n iná láàrin ìgbẹ́; bí ó ti wò ó, ó rí i pé iná ń jó nítòótọ́, ṣugbọn igbó náà kò jóná. Mose bá wí ninu ara rẹ̀ pé, “N óo súnmọ́ kinní yìí, mo fẹ́ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná fi ń jó tí igbó kò sì fi jóná.” Nígbà tí Ọlọrun rí i pé ó súnmọ́ ọn láti wo ohun ìyanu náà, Ọlọrun pè é láti inú igbó náà, ó ní, “Mose! Mose!” Mose dáhùn pé, “Èmi nìyí.” Ọlọrun ní, “Má ṣe súnmọ́ tòsí ibí, bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé, ilẹ̀ tí o dúró sí yìí, ilẹ̀ mímọ́ ni.” Ọlọrun tún fi kún un pé, “Èmi ni Ọlọrun baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu.” Mose bá bo ojú rẹ̀ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á láti wo Ọlọrun. Lẹ́yìn náà OLUWA dáhùn pé, “Mo ti rí ìpọ́njú àwọn eniyan mi tí wọ́n wà ní Ijipti, mo sì ti gbọ́ igbe wọn, nítorí ìnilára àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́, mo mọ irú ìyà tí wọn ń jẹ, mo sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti wá gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, ati láti kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dára, tí ó sì tẹ́jú, ilẹ̀ tí ó lẹ́tù lójú tí ó kún fún wàrà ati oyin, àní, ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Hifi ati ti àwọn ará Jebusi. Igbe àwọn eniyan Israẹli ti gòkè tọ̀ mí wá, mo sì ti rí bí àwọn ará Ijipti ṣe ń ni wọ́n lára. Wá, n óo rán ọ sí Farao, kí o lè lọ kó àwọn eniyan mi, àwọn ọmọ Israẹli, jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.” Ṣugbọn Mose dá Ọlọrun lóhùn pé, “Ta ni mo jẹ́, tí n óo fi wá tọ Farao lọ pé mo fẹ́ kó àwọn ọmọ Israẹli kúrò ní ilẹ̀ Ijipti?” Ọlọrun bá dá a lóhùn pé, “N óo wà pẹlu rẹ, ohun tí yóo sì jẹ́ àmì fún ọ, pé èmi ni mo rán ọ ni pé, nígbà tí o bá ti kó àwọn eniyan náà kúrò ní Ijipti, ẹ óo sin Ọlọrun ní orí òkè yìí.” Mose tún bi Ọlọrun pé, “Bí mo bá dé ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli, tí mo sì wí fún wọn pé, ‘Ọlọrun àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ bí wọ́n bá wá bi mí pé ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni kí n wí fún wọn?” Ọlọrun dá Mose lóhùn pé, “ÈMI NI ẸNI TÍ MO JẸ́. Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘ÈMI NI ni ó rán mi sí yín.’ ” Ọlọrun tún fi kún un fún Mose pé kí ó sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó rán òun sí wọn. Ó ní orúkọ òun nìyí títí ayérayé, orúkọ yìí ni wọn óo sì máa fi ranti òun láti ìrandíran. Ó ní, “Lọ kó gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, kí o sì sọ fún wọn pé, èmi OLUWA, Ọlọrun àwọn baba yín, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, ni ó farahàn ọ́, ati pé, mo ti ń ṣàkíyèsí wọn, mo ti rí ohun tí àwọn ará Ijipti ti ṣe sí wọn.