ẸKISODU 27
27
Pẹpẹ
(Eks 38:1-7)
1“Igi akasia ni kí o fi ṣe pẹpẹ, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ marun-un; kí òòró ati ìbú pẹpẹ náà rí bákan náà, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ mẹta. 2Yọ ìwo kọ̀ọ̀kan sí igun rẹ̀ mẹrẹẹrin, àṣepọ̀ ni kí o ṣe àwọn ìwo náà mọ́ pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo gbogbo rẹ̀. 3Fi idẹ ṣe ìkòkò láti máa kó eérú orí pẹpẹ sí, fi idẹ ṣe ọkọ́, àwo kòtò, ọ̀kọ̀ tí wọ́n fi ń gún ẹran ẹbọ ati àwo ìfọnná, idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò pẹpẹ náà. 4Idẹ ni kí o fi ṣe asẹ́ ààrò rẹ̀, kí o sì ṣe òrùka idẹ mẹrin, ọ̀kọ̀ọ̀kan sí igun mẹrẹẹrin asẹ́ náà. 5Ti asẹ́ idẹ náà bọ abẹ́ etí pẹpẹ, tí yóo fi jẹ́ pé asẹ́ náà yóo dé agbede meji pẹpẹ náà sísàlẹ̀. 6Fi igi akasia ṣe ọ̀pá pẹpẹ, kí o sì yọ́ idẹ bo ọ̀pá náà. 7Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ, tí ọ̀pá yóo fi wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji pẹpẹ náà nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbé e. 8Fi pákó ṣe pẹpẹ náà, kí o sì jẹ́ kí ó jin kòtò, bí mo ti fi hàn ọ́ ní orí òkè, bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí o ṣe é.
Àgbàlá fún Àgọ́ Wíwà OLUWA
(Eks 38:9-20)
9“Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, 10àwọn òpó rẹ̀ yóo jẹ́ ogún, ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ ogún bákan náà, idẹ ni o óo fi ṣe wọ́n, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ ati òpó rẹ̀. 11Bákan náà, aṣọ tí o óo ta sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgbàlá náà yóo gùn ní ọgọrun-un igbọnwọ, àwọn òpó ti ẹ̀gbẹ́ náà yóo jẹ́ ogún bákan náà, pẹlu ogún ìtẹ́lẹ̀ tí a fi idẹ ṣe, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe ìkọ́ ati òpó wọn. 12Aṣọ títa yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, yóo ní òpó mẹ́wàá, òpó kọ̀ọ̀kan yóo ní ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan. 13Fífẹ̀ àgbàlá náà, láti iwájú títí dé ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ. 14Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta. 15Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ẹnu ọ̀nà náà, òun náà yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo sì ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta bákan náà. 16Ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà yóo ní aṣọ títa kan tí yóo gùn ní ogún igbọnwọ, aṣọ aláwọ̀ aró, èyí tí ó ní àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa fòò ati aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa náà, kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí etí rẹ̀, kí ó ní òpó mẹrin ati ìtẹ́lẹ̀ mẹrin. 17Fadaka ni kí o fi bo gbogbo òpó inú àgọ́ náà, fadaka náà ni kí o sì fi ṣe gbogbo ìkọ́ àwọn òpó náà, àfi àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni kí o fi idẹ ṣe. 18Gígùn àgbàlá náà yóo jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ marun-un pẹlu aṣọ títa tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ati ìtẹ́lẹ̀ idẹ. 19Idẹ ni kí o fi ṣe gbogbo àwọn ohun èlò inú àgọ́ náà ati gbogbo èèkàn rẹ̀, ati gbogbo èèkàn àgbàlá náà.
Ìtọ́jú Fìtílà
(Lef 24:1-4)
20“Pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli pé kí wọn mú ojúlówó òróró olifi wá fún títan iná, kí wọ́n lè gbé fìtílà kan kalẹ̀ tí yóo máa wà ní títàn nígbà gbogbo. 21Yóo wà ninu àgọ́ àjọ, lọ́wọ́ ìta aṣọ títa tí ó wà níwájú àpótí ẹ̀rí, kí Aaroni ati àwọn ọmọ rẹ̀ máa tọ́jú rẹ̀ níwájú OLUWA láti àṣáálẹ́ títí di òwúrọ̀. Kí àwọn eniyan Israẹli sì máa pa ìlànà náà mọ́ títí lae, láti ìrandíran.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
ẸKISODU 27: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010