ẸKISODU 12:23-51

ẸKISODU 12:23-51 YCE

Nítorí pé, OLUWA yóo rékọjá, yóo sì pa àwọn ará Ijipti. Ṣugbọn nígbà tí ó bá rí ẹ̀jẹ̀ lára àtẹ́rígbà ati lára òpó ẹnu ọ̀nà mejeeji, OLUWA yóo ré ẹnu ọ̀nà náà kọjá, kò sì ní jẹ́ kí apanirun wọ ilé yín láti pa yín. Ẹ̀yin ati àwọn arọmọdọmọ yín, ẹ gbọdọ̀ máa pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin títí lae. Nígbà tí ẹ bá sì dé ilẹ̀ tí OLUWA yóo fún yín gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí, ẹ gbọdọ̀ máa ṣe ìsìn yìí. Nígbà tí àwọn ọmọ yín bá sì bi yín léèrè pé, ‘Kí ni ìtumọ̀ ìsìn yìí?’ ẹ óo dá wọn lóhùn pé, ‘Ẹbọ ìrékọjá OLUWA ni, nítorí pé ó ré ilé àwọn eniyan Israẹli kọjá ní Ijipti, nígbà tí ó ń pa àwọn ará Ijipti, ṣugbọn ó dá àwọn ilé wa sí.’ ” Àwọn eniyan Israẹli wólẹ̀, wọ́n sì sin OLUWA. Wọ́n bá lọ, wọ́n sì ṣe bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose ati Aaroni. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́ òru, OLUWA lu gbogbo àwọn àkọ́bí ilẹ̀ Ijipti pa, ó bẹ̀rẹ̀ láti orí àrẹ̀mọ ọba Farao tí ó wà lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí ẹrú tí ó wà ninu ọgbà ẹ̀wọ̀n, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. Farao bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, òun ati gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀, ati gbogbo àwọn ará Ijipti. Igbe ẹkún ńlá sì sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, nítorí pé kò sí ẹyọ ilé kan tí eniyan kò ti kú. Farao bá ranṣẹ pe Mose ati Aaroni ní òru ọjọ́ náà, ó ní, “Ẹ gbéra, ẹ máa lọ, ẹ jáde kúrò láàrin àwọn eniyan mi, ati ẹ̀yin ati àwọn eniyan Israẹli, ẹ lọ sin OLUWA yín bí ẹ ti wí. Ẹ máa kó àwọn agbo mààlúù yín lọ, ati agbo aguntan yín, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti wí. Ẹ máa lọ; ṣugbọn ẹ súre fún èmi náà!” Àwọn ará Ijipti bá ń kán àwọn eniyan náà lójú láti tètè máa lọ. Wọ́n ní bí wọn kò bá tètè lọ, gbogbo àwọn ni àwọn yóo di òkú. Àwọn eniyan náà bá mú àkàrà tí wọ́n ti pò, ṣugbọn tí wọn kò tíì fi ìwúkàrà sí, wọ́n sì fi aṣọ so ọpọ́n ìpòkàrà wọn, wọ́n gbé e kọ́ èjìká. Àwọn eniyan náà ṣe bí Mose ti sọ fún wọn, olukuluku wọn ti tọ àwọn ará Ijipti lọ, wọ́n ti tọrọ ohun ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà ati aṣọ. OLUWA sì jẹ́ kí wọ́n bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, gbogbo ohun tí wọ́n tọrọ pátá ni àwọn ará Ijipti fún wọn. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn eniyan Israẹli ṣe, tí wọ́n sì fi kó ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ará Ijipti lọ. Àwọn eniyan Israẹli gbéra, wọ́n rìn láti Ramesesi lọ sí Sukotu. Iye àwọn eniyan náà tó ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ (600,000) ọkunrin, láìka àwọn obinrin ati àwọn ọmọde. Ọpọlọpọ àwọn mìíràn ni wọ́n bá wọn lọ, pẹlu ọpọlọpọ ẹran ọ̀sìn ati agbo aguntan ati agbo mààlúù. Wọ́n mú ìyẹ̀fun tí wọ́n ti pò ní ilẹ̀ Ijipti, wọ́n fi ṣe burẹdi tí kò ní ìwúkàrà, nítorí pé lílé ni àwọn ará Ijipti lé wọn jáde, wọn kò sì lè dúró mú oúnjẹ mìíràn lọ́wọ́. Àkókò tí àwọn ọmọ Israẹli gbé ní ilẹ̀ Ijipti jẹ́ irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430). Ọjọ́ tí ó pé irinwo ọdún ó lé ọgbọ̀n (430) gééré, tí wọ́n ti dé ilẹ̀ Ijipti; ni àwọn eniyan OLUWA jáde kúrò níbẹ̀. Ṣíṣọ́ ni OLUWA ń ṣọ́ wọn ní gbogbo òru ọjọ́ náà títí ó fi kó wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Àwọn eniyan Israẹli ya alẹ́ ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún OLUWA, láti ìrandíran wọn. Ní ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣọ́nà ní òru ní ìrántí òru àyájọ́ ọjọ́ náà. OLUWA sọ fún Mose ati Aaroni pé, “Òfin àjọ ìrékọjá nìwọ̀nyí: àlejò kankan kò gbọdọ̀ ba yín jẹ oúnjẹ àjọ ìrékọjá. Ṣugbọn àwọn ẹrú tí ẹ fi owó rà, tí ẹ sì kọ ní ilà abẹ́ lè bá yín jẹ ẹ́. Àlejò kankan tabi alágbàṣe kò gbọdọ̀ ba yín jẹ ẹ́. Ilé tí ẹ bá ti se oúnjẹ yìí ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ gbogbo rẹ̀, ẹ kò gbọdọ̀ mú ninu ẹran rẹ̀ jáde, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọ́ egungun rẹ̀. Gbogbo ìjọ eniyan Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe ìrántí ọjọ́ yìí. Bí àlejò kan bá wọ̀ sí ilé yín, tí ó bá sì fẹ́ bá yín ṣe àjọ̀dún àjọ ìrékọjá, ó gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọkunrin inú ìdílé rẹ̀ ní ilà abẹ́, lẹ́yìn náà, ó lè ba yín ṣe àjọ̀dún náà, òun náà yóo dàbí olùgbé ilẹ̀ náà, ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí kò bá kọ ilà abẹ́ kò gbọdọ̀ jẹ ninu àjọ ìrékọjá náà. Ati ẹ̀yin, ati àlejò tí ń gbé ààrin yín, òfin kan ṣoṣo ni ó de gbogbo yín.” Gbogbo àwọn eniyan Israẹli bá ṣe bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose ati Aaroni. Ní ọjọ́ yìí gan-an ni OLUWA mú àwọn ẹ̀yà Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

Àwọn ètò kíkà ọ̀fé àti àyọkà tó ní ṣe pẹ̀lú ẸKISODU 12:23-51