ẸKISODU 11

11
Mose Kéde Ikú Àwọn Àkọ́bí
1Nígbà tí ó yá, OLUWA sọ fún Mose pé, “Ó ku ìyọnu kan péré, tí n óo mú bá Farao ati ilẹ̀ Ijipti, lẹ́yìn náà yóo jẹ́ kí ẹ lọ. Nígbà tí ó bá gbà kí ẹ lọ, òun fúnra rẹ̀ ni yóo tì yín jáde patapata. 2Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí olukuluku tọ aládùúgbò rẹ̀ lọ, ati ọkunrin ati obinrin wọn, kí wọ́n lọ tọrọ nǹkan ọ̀ṣọ́ fadaka ati ti wúrà.” 3OLUWA jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli bá ojurere àwọn ará Ijipti pàdé, ati pé àwọn ará Ijipti ati àwọn ẹmẹ̀wà Farao ati àwọn eniyan rẹ̀ ka Mose kún eniyan pataki.
4Mose bá sọ fún Farao pé, “OLUWA ní, nígbà tí ó bá di ọ̀gànjọ́ òru, òun yóo la ilẹ̀ Ijipti kọjá, 5gbogbo àkọ́bí ní ilẹ̀ Ijipti ni yóo sì kú. Bẹ̀rẹ̀ láti orí àkọ́bí Farao, tí ó jókòó lórí ìtẹ́, títí kan àkọ́bí iranṣẹbinrin tí ń lọ ọkà, ati àkọ́bí gbogbo ẹran ọ̀sìn. 6Ariwo ẹkún ńlá yóo sọ ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti, irú èyí tí kò ṣẹlẹ̀ rí, tí kò sì tún ní sí irú rẹ̀ mọ́. 7Ṣugbọn ajá kò tilẹ̀ ní gbó ẹnikẹ́ni tabi ẹran ọ̀sìn kan, jákèjádò ààrin àwọn ọmọ Israẹli; kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA fi ìyàtọ̀ sí ààrin àwọn ará Ijipti ati àwọn ọmọ Israẹli. 8Gbogbo àwọn ẹmẹ̀wà rẹ wọnyi yóo sì tọ̀ mí wá, wọn yóo fi orí balẹ̀ fún mi, wọn yóo wí pé kí n máa lọ, èmi ati gbogbo àwọn eniyan mi! Lẹ́yìn náà ni n óo jáde lọ.” Mose bá fi tìbínú-tìbínú jáde kúrò níwájú Farao.
9Lẹ́yìn náà OLUWA sọ fún Mose pé, “Farao kò ní gba ọ̀rọ̀ rẹ, kí iṣẹ́ ìyanu mi baà lè di pupọ ní ilẹ̀ Ijipti.” 10Mose ati Aaroni ṣe gbogbo iṣẹ́ ìyanu tí wọn ṣe níwájú Farao, ṣugbọn OLUWA sì mú kí ọkàn Farao le, kò sì jẹ́ kí àwọn eniyan Israẹli lọ kúrò ní ilẹ̀ rẹ̀.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ẸKISODU 11: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀