Mò ń gbadura pé kí Ọlọrun, Baba Oluwa wa Jesu Kristi, Baba ológo, lè fun yín ní ẹ̀mí ọgbọ́n, kí ó sì jẹ́ kí ẹ ní ìmọ̀ tí ó kún nípa òun alára. Mo sì tún ń gbadura pé kí ó lè là yín lójú ẹ̀mí, kí ẹ lè mọ ìrètí tí ó ní tí ó fi pè yín, kí ẹ sì lè mọ ògo tí ó wà ninu ogún rẹ̀ tí yóo pín fun yín pẹlu àwọn onigbagbọ, ati bí agbára rẹ̀ ti tóbi tó fún àwa tí a gbàgbọ́, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ títóbi agbára rẹ̀. Ó fi agbára yìí hàn ninu Kristi nígbà tí ó jí i dìde ninu òkú, tí ó mú un jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lọ́run. Ó ga ju gbogbo àwọn ọlọ́lá ati aláṣẹ ati àwọn alágbára ati àwọn olóye tí wọ́n wà lójú ọ̀run lọ. Ó tún ga ju gbogbo orúkọ tí eniyan lè dá lọ, kì í ṣe ní ayé yìí nìkan, ṣugbọn ati ní ayé tí ń bọ̀ pẹlu.
Kà EFESU 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: EFESU 1:17-21
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò