Gbogbo nǹkan wọnyi ni mo fi sọ́kàn. Mo yẹ gbogbo rẹ̀ wò, bí ó ti jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn olódodo, àwọn ọlọ́gbọ́n, ati gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn wà. Bí ti ìfẹ́ ni, bí ti ìkórìíra ni, ẹnìkan kò mọ̀. Asán ni gbogbo ohun tí ó wà níwájú wọn. Nítorí nǹkankan náà ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn: ati olódodo ati ẹlẹ́ṣẹ̀, ati eniyan rere ati eniyan burúkú, ati ẹni mímọ́, ati ẹni tí kò mọ́, ati ẹni tí ń rúbọ ati ẹni tí kì í rú. Bí eniyan rere ti rí, bẹ́ẹ̀ ni ẹlẹ́ṣẹ̀ náà rí. Bákan náà ni ẹni tí ń búra ati ẹni tí ó takété sì ìbúra. Nǹkankan tí ó burú, ninu àwọn nǹkan tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé ni pé, ìpín kan náà ni gbogbo ọmọ aráyé ní, ọkàn gbogbo eniyan kún fún ibi, ìwà wèrè sì wà lọ́kàn wọn; lẹ́yìn náà, wọn a sì kú. Ṣugbọn ìrètí ń bẹ fún ẹni tí ó wà láàyè, nítorí pé ààyè ajá wúlò ju òkú kinniun lọ. Nítorí alààyè mọ̀ pé òun óo kú, ṣugbọn òkú kò mọ nǹkankan mọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní èrè kan mọ́, a kò sì ní ranti wọn mọ́. Ìfẹ́, ati ìkórìíra, ati ìlara wọn ti parun, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ laelae ninu ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nílé ayé.
Máa lọ fi tayọ̀tayọ̀ jẹ oúnjẹ rẹ, sì máa mu ọtí waini rẹ pẹlu ìdùnnú, nítorí Ọlọrun ti fi ọwọ́ sí ohun tí ò ń ṣe. Máa wọ aṣọ àríyá nígbà gbogbo, sì máa fi òróró pa irun rẹ dáradára. Máa gbádùn ayé pẹlu aya rẹ, olólùfẹ́ rẹ, ní gbogbo ọjọ́ asán tí Ọlọrun fún ọ nílé ayé. Nítorí ìpín tìrẹ nìyí láyé ninu làálàá tí ò ń ṣe. Ohunkohun tí o bá ti dáwọ́ lé, fi gbogbo agbára rẹ ṣe é nítorí, kò sí iṣẹ́, tabi èrò, tabi ìmọ̀, tabi ọgbọ́n, ní isà òkú tí ò ń lọ.
Bákan náà, mo rí i pé, láyé, ẹni tí ó yára, tí ó lè sáré, lè má borí ninu eré ìje, alágbára lè jagun kó má ṣẹgun, ọlọ́gbọ́n lè má rí oúnjẹ jẹ, eniyan lè gbọ́n kó lóye, ṣugbọn kí ó má lówó lọ́wọ́, ẹni tí ó mọ iṣẹ́ ṣe sì lè má ní ìgbéga, àjálù ati èèṣì lè ṣẹlẹ̀ sí ẹnikẹ́ni. Kò sí ẹni tí ó mọ àkókò tirẹ̀. Bíi kí ẹja kó sinu àwọ̀n burúkú, tabi kí ẹyẹ kó sinu pańpẹ́, ni tàkúté ibi ṣe máa ń mú eniyan, nígbà tí àkókò ibi bá dé bá wọn.
Mo tún rí àpẹẹrẹ ọgbọ́n kan nílé ayé, ó sì jẹ́ ohun ribiribi lójú mi. Ìlú kékeré kan wà, tí eniyan kò pọ̀ ninu rẹ̀, ọba ńlá kan wà, ó dótì í, ó sì mọ òkítì sí ara odi rẹ̀. Ọkunrin ọlọ́gbọ́n kan wà níbẹ̀ tí ó jẹ́ talaka, ó gba ìlú náà sílẹ̀ pẹlu ọgbọ́n rẹ̀, ṣugbọn ẹnìkan kò ranti talaka náà mọ́. Sibẹsibẹ, mo rí i pé ọgbọ́n ju agbára lọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ka ọgbọ́n ọkunrin yìí kún, tí kò sì sí ẹni tí ó fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ tí ọlọ́gbọ́n bá sọ, ó dára ju igbe aláṣẹ láàrin àwọn òmùgọ̀ lọ. Ọgbọ́n dára ju ohun ìjà ogun lọ, ṣugbọn ẹlẹ́ṣẹ̀ kanṣoṣo a máa ba nǹkan ribiribi jẹ́.