DIUTARONOMI 29

29
Àdéhùn OLUWA pẹlu Israẹli ní Ilẹ̀ Moabu
1OLUWA pàṣẹ fún Mose pé kí ó bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu mìíràn ní ilẹ̀ Moabu, yàtọ̀ sí èyí tí ó ti bá wọn dá ní òkè Horebu.
2Mose pe gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí OLUWA ṣe sí Farao ati àwọn iranṣẹ rẹ̀, ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti. 3Ẹ fi ojú yín rí àwọn ìdààmú ńláńlá tí ó bá wọn, ati àwọn iṣẹ́ ìyanu ńlá tí OLUWA ṣe. 4Ṣugbọn títí di òní yìí, OLUWA kò tíì jẹ́ kí òye ye yín, ojú yín kò ríran, bẹ́ẹ̀ ni etí yín kò gbọ́ràn. 5Odidi ogoji ọdún ni mo fi ko yín la ààrin aṣálẹ̀ kọjá. Aṣọ kò gbó mọ yín lára, bẹ́ẹ̀ ni bàtà kò gbó mọ yín lẹ́sẹ̀. 6Ẹ kò jẹ oúnjẹ gidi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò mu ọtí waini tabi ọtí líle, kí ẹ lè mọ̀ pé OLUWA ni OLUWA Ọlọrun yín. 7Nígbà tí ẹ dé ibí yìí, Sihoni, ọba Heṣiboni ati Ogu, ọba Baṣani gbógun tì wá, ṣugbọn a ṣẹgun wọn.#a Nọm 21:21-30 b Nọm 21:31-35 8A gba ilẹ̀ wọn, a sì fi fún ẹ̀yà Reubẹni, ati ẹ̀yà Gadi ati ìdajì ẹ̀yà Manase, gẹ́gẹ́ bí ìpín tiwọn.#Nọm 32:33 9Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí ẹ máa tẹ̀lé majẹmu yìí, kí ohun gbogbo tí ẹ bá dáwọ́lé lè máa yọrí sí rere.
10“Gbogbo yín pátá ni ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ati gbogbo àwọn olórí ninu àwọn ẹ̀yà yín, ati àwọn àgbààgbà ati àwọn olóyè ati àwọn ọkunrin Israẹli. 11Àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín, àwọn aya yín, ati àwọn àlejò tí wọn ń gbé orí ilẹ̀ yín; àwọn tí wọn ń wá igi fun yín, ati àwọn tí wọn ń pọnmi fun yín. 12Kí gbogbo yín lè bá OLUWA Ọlọrun yín dá majẹmu lónìí, 13kí ó lè fi ìdí yín múlẹ̀ bí eniyan rẹ̀, kí ó sì máa jẹ́ Ọlọrun yín; gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí fun yín, ati bí ó ti búra fún Abrahamu, Isaaki, ati Jakọbu àwọn baba ńlá yín. 14‘Kìí ṣe ẹ̀yin nìkan ni mò ń bá dá majẹmu yìí, tí mo sì ń búra fún, 15ṣugbọn ati àwọn tí wọn kò sí níhìn-ín lónìí, ati ẹ̀yin alára tí ẹ dúró níwájú OLUWA Ọlọrun yín lónìí, ni majẹmu náà wà fún.’
16“Ẹ̀yin náà mọ̀ bí ayé wa ti rí ní ilẹ̀ Ijipti, ati bí a ti la ààrin àwọn orílẹ̀-èdè tí a gbà kọjá. 17Ẹ sì ti rí àwọn ohun ìríra wọn: àwọn oriṣa wọn tí wọ́n fi igi gbẹ́, èyí tí wọ́n fi òkúta gbẹ́, èyí tí wọ́n fi fadaka ṣe, ati èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe. 18Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra yín, kí á má ṣe rí ẹnikẹ́ni ninu yín, kì báà ṣe ọkunrin tabi obinrin, tabi ìdílé kan, tabi ẹ̀yà kan, tí ọkàn rẹ̀ yóo yipada kúrò lọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun yín lónìí, tí yóo sì lọ máa bọ àwọn oriṣa tí àwọn orílẹ̀-èdè náà ń bọ. Nítorí pé, irú ẹni bẹ́ẹ̀ yóo dàbí igi tí ń so èso tí ó korò, tí ó sì ní májèlé ninu.#Heb 12:15 19Kí irú ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ majẹmu má baà dá ara rẹ̀ lọ́kàn le pé ‘Kò séwu, bí mo bá fẹ́ mo lè ṣe orí kunkun kí n sì máa tẹ̀lé ìmọ̀ ara mi.’ Èyí yóo kó ìparun bá gbogbo yín, ati àwọn tí wọn ń ṣe ibi ati àwọn tí wọn ń ṣe rere. 20OLUWA kò ní dáríjì olúwarẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ibinu ńlá OLUWA ni yóo bá a. Gbogbo àwọn ègún tí a kọ sinu ìwé yìí yóo ṣẹ sí i lára, OLUWA yóo sì pa orúkọ olúwarẹ̀ rẹ́ kúrò láyé. 21OLUWA yóo dojú kọ òun nìkan, láti ṣe é ní ibi láàrin gbogbo ẹ̀yà Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ègún tí ó wà ninu majẹmu, tí a kọ sinu ìwé òfin yìí.
22“Nígbà tí àwọn arọmọdọmọ yín tí wọn kò tíì bí, ati àwọn àlejò tí wọ́n bá wá láti ilẹ̀ òkèèrè bá rí ìpọ́njú, ati àrùn tí OLUWA yóo dà bo ilẹ̀ náà, 23tí wọ́n bá rí i tí gbogbo ilẹ̀ náà ti di imí ọjọ́ ati iyọ̀, tí gbogbo rẹ di eérú, tí koríko kankan kò lè hù lórí rẹ̀, bíi ìlú Sodomu ati Gomora, Adima ati Seboimu, tí OLUWA fi ibinu ńlá parẹ́, 24gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni yóo máa bèèrè pé, ‘Kí ló dé tí OLUWA fi sọ ilẹ̀ yìí dà báyìí? Kí ló dé tí ibinu ńlá OLUWA fi dé sórí ilẹ̀ yìí?’ 25Àwọn eniyan yóo sì máa dáhùn pé, ‘Nítorí pé wọn kò mú majẹmu OLUWA Ọlọrun ṣẹ, tí ó bá àwọn baba wọn dá nígbà tí ó kó wọn jáde ní ilẹ̀ Ijipti. 26Wọ́n ń bọ àwọn oriṣa tí wọn kò mọ̀ rí, tí OLUWA kò sì fi lé wọn lọ́wọ́. 27Ìdí nìyí tí inú fi bí OLUWA sí ilẹ̀ yìí, tí ó sì mú gbogbo ègún tí a kọ sinu ìwé yìí ṣẹ lé wọn lórí. 28OLUWA sì fi ibinu ńlá ati ìrúnú lé wọn kúrò lórí ilẹ̀ wọn, ó sì fọ́n wọn dà sórí ilẹ̀ mìíràn gẹ́gẹ́ bí ó ti rí lónìí.’
29“Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí.#Jẹn 19:24-25

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 29: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀