DIUTARONOMI 27

27
Ìlànà nípa Kíkọ Òfin Ọlọrun Sára Òkúta
1Mose, pẹlu gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli, sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ máa pa gbogbo òfin tí mo fun yín lónìí mọ́. 2Ní ọjọ́ tí ẹ bá kọjá odò Jọdani, tí ẹ bá ti wọ inú ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ẹ to òkúta ńláńlá jọ kí ẹ fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ.#Joṣ 8:30-32 3Ẹ kọ gbogbo òfin wọnyi sára rẹ̀, nígbà tí ẹ bá ń rékọjá lọ láti wọ ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín yóo fun yín, ilẹ̀ tí ó kún fún wàrà ati oyin, gẹ́gẹ́ bí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti ṣèlérí fun yín. 4Nígbà tí ẹ bá rékọjá sí òdìkejì odò Jọdani, ẹ to àwọn òkúta tí mo paláṣẹ fun yín lónìí jọ lórí òkè Ebali, kí ẹ sì fi ohun tí wọ́n fi ń rẹ́ ilé rẹ́ ẹ. 5Ẹ fi òkúta kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA níbẹ̀; ẹ kò gbọdọ̀ fi irin gbẹ́ òkúta náà rárá. 6Òkúta tí wọn kò gbẹ́ ni kí ẹ fi kọ́ pẹpẹ kan fún OLUWA Ọlọrun yín kí ẹ sì rú ẹbọ sísun sí i lórí rẹ̀.#Eks 20:25 7Ẹ rú ẹbọ alaafia, kí ẹ jẹ ẹ́ níbẹ̀, kí ẹ sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín. 8Ẹ kọ gbogbo àwọn òfin wọnyi sára òkúta náà, ẹ kọ wọ́n kí wọ́n hàn ketekete.”
9Mose ati àwọn alufaa, ọmọ Lefi, bá wí fún gbogbo ọmọ Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ jẹ́ẹ́, kí ẹ sì gbọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, òní ni ẹ di eniyan OLUWA Ọlọrun yín. 10Nítorí náà ẹ gbọdọ̀ máa gbọ́ràn sí OLUWA Ọlọrun yín lẹ́nu, kí ẹ sì máa pa òfin ati ìdájọ́ rẹ̀ mọ́, bí èmi Mose ti pàṣẹ fun yín lónìí.”
Àwọn Ègún fún Àìgbọràn
11Mose bá pàṣẹ fún àwọn eniyan náà ní ọjọ́ kan náà, ó ní, 12“Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre.#Diut 11:29; Joṣ 8:33-35 13Àwọn ẹ̀yà Reubẹni, ẹ̀yà Gadi, ti Aṣeri, ti Sebuluni, ti Dani ati ti Nafutali yóo sì dúró lórí òkè Ebali láti búra. 14Àwọn ọmọ Lefi yóo wí ketekete fún gbogbo àwọn ọmọ Israẹli pé:
15“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yá ère gbígbẹ́ tabi ère tí wọ́n fi irin rọ. Ohun ìríra ni lójú OLUWA, pé kí àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà fi ọwọ́ gbẹ́ nǹkan, kí ẹnìkan wá gbé e kalẹ̀ níkọ̀kọ̀, kí ó máa bọ ọ́.’#Eks 20:4; 34:17; Lef 19:4; 26:1; Diut 4:15-18; 5:8
“Gbogbo àwọn eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
16“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá tàbùkù baba tabi ìyá rẹ̀.’#Eks 20:12; Diut 5:16
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
17“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá yẹ ààlà ilẹ̀ ẹnìkejì rẹ̀.’#Diut 19:14
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
18“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣi afọ́jú lọ́nà.’#Lef 19:14
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
19“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹni tí ó bá yí ìdájọ́ òdodo tí ó tọ́ sí àlejò po, tabi ti aláìní baba, tabi ti opó.’#Eks 22:21;23:9; Lef 19:33-34; Diut 24:17-18
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
20“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀, nítorí pé ó dójúti baba rẹ̀.’
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
21“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹranko lòpọ̀.’#Eks 22:19; Lef 18:23; 20:15
“Gbogbo eniyan yóo dáhùn pé, ‘Amin.’
22“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá arabinrin rẹ̀ lòpọ̀, kì báà jẹ́ ọmọ ìyá rẹ̀ tabi ọmọ baba rẹ̀.’#Lef 18:9; 20:17
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
23“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ìyá aya rẹ̀ lòpọ̀.’#Lef 18:17; 20:14
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
24“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá pa aládùúgbò rẹ̀ níkọ̀kọ̀.’
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
25“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa aláìṣẹ̀.’
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’
26“ ‘Ẹni ìfibú ni ẹnikẹ́ni tí kò bá pa gbogbo àwọn òfin yìí mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn.’#Gal 3:10
“Gbogbo eniyan yóo sì dáhùn pé, ‘Amin.’

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 27: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀