DIUTARONOMI 17

17
1“Ẹ kò gbọdọ̀ fi mààlúù tabi aguntan tí ó ní àbààwọ́n rúbọ sí OLUWA Ọlọrun yín nítorí pé ohun ìríra ni ó jẹ́ fún un.
2“Bí ọkunrin kan tabi obinrin kan láàrin àwọn ìlú tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín bá ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA Ọlọrun yín, nípa pé ó da majẹmu rẹ̀, 3bí ó bá lọ bọ oriṣa, kì báà ṣe oòrùn, tabi òṣùpá, tabi ọ̀kan ninu àwọn nǹkan mìíràn tí ó wà ní ojú ọ̀run, tí mo ti pàṣẹ pé ẹ kò gbọdọ̀ bọ; 4bí wọn bá sọ fun yín tabi ẹ gbọ́ nípa rẹ̀, ẹ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ wádìí. Bí ó bá jẹ́ pé òtítọ́ ni, tí ìdánilójú sì wà pé ohun ìríra bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ní Israẹli,#Eks 22:20 5ẹ mú ẹni tí ó ṣe ohun burúkú náà jáde lọ sí ẹnu ibodè yín, kí ẹ sì sọ ọ́ ní òkúta pa. 6Ẹlẹ́rìí gbọdọ̀ tó meji tabi mẹta kí wọ́n tó lè pa ẹnikẹ́ni fún irú ẹ̀sùn bẹ́ẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ pa eniyan nítorí ẹ̀rí ẹnìkan ṣoṣo.#Nọm 35:30; Diut 19:15; Mat 18: 16; 2 Kọr 13:1; 1 Tim 5:19; Heb 10:28 7Àwọn ẹlẹ́rìí ni wọ́n gbọdọ̀ kọ́kọ́ sọ òkúta lu ẹni náà, lẹ́yìn náà ni gbogbo eniyan yóo tó kó òkúta bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ẹni burúkú náà kúrò láàrin yín.#1 Kọr 5:13
8“Bí ẹjọ́ kan bá ta kókó tí ó ní àríyànjiyàn ninu, tí ó sì ṣòro láti dá fún àwọn onídàájọ́ yín, kì báà jẹ mọ́ ṣíṣèèṣì paniyan ati mímọ̀ọ́nmọ̀ paniyan, tabi ẹ̀tọ́ lórí ohun ìní ẹni; tabi tí ẹnìkan bá ṣe ohun àbùkù kan sí ẹlòmíràn, ẹ óo lọ sí ibi tí OLUWA Ọlọrun yín yóo yàn, pé kí ẹ ti máa jọ́sìn. 9Ẹ tọ àwọn alufaa ọmọ Lefi lọ, kí ẹ sì kó ẹjọ́ yín lọ sí ọ̀dọ̀ ẹni tí ó wà ní ipò onídàájọ́ ní àkókò náà. Ẹ ro ẹjọ́ yín fún wọn, wọn yóo sì bá yín dá a. 10Ohunkohun tí wọ́n bá sọ fun yín ní ibi tí OLUWA bá yàn ni ẹ gbọdọ̀ ṣe. Ẹ gbọdọ̀ ṣọ́ra, kí ẹ sì ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá ní kí ẹ ṣe. 11Ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín ni kí ẹ gbà, kí ẹ sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà tí wọ́n bá là sílẹ̀. Ẹ kò gbọdọ̀ yà sí ọ̀tún tabi sí òsì ninu ẹjọ́ tí wọ́n bá dá fun yín. 12Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe oríkunkun sí ẹni tí ó jẹ́ onídàájọ́ nígbà náà, tabi alufaa tí ó wà lẹ́nu iṣẹ́ ní àkókò náà, pípa ni kí ẹ pa á; bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe yọ ohun burúkú náà kúrò láàrin Israẹli. 13Gbogbo àwọn eniyan ni yóo gbọ́, ẹ̀rù yóo bà wọ́n; ẹnikẹ́ni kò sì ní ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́.
Ìkìlọ̀ nípa Yíyan Ọba
14“Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín, tí ẹ bá gbà á, tí ẹ sì ń gbé inú rẹ̀, tí ẹ bá wí nígbà náà pé, ‘A óo fi ẹnìkan jọba lórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí wọ́n yí wa ká,’ 15ẹ lè fi ẹnikẹ́ni tí OLUWA Ọlọrun yín bá yàn fun yín jọba, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín ni ẹ gbọdọ̀ fi jọba, ẹ kò gbọdọ̀ fi àlejò, tí kì í ṣe ọ̀kan ninu àwọn arakunrin yín jọba.#1Sam 8:5 17:16; 1A. Ọba 10:28; 2Kron 1:16; 9:28 16Ṣugbọn kò gbọdọ̀ máa kó ẹṣin jọ fún ara rẹ̀ tabi kí ó mú kí àwọn eniyan náà pada lọ sí ilẹ̀ Ijipti láti ra ẹṣin kún ẹṣin, níwọ̀n ìgbà tí OLUWA ti wí fun yín pé, ‘Ẹ kò gbọdọ̀ pada lọ sí ibẹ̀ mọ́.’ 17Kò gbọdọ̀ kó aya jọ kí ọkàn rẹ̀ má baà yipada; bẹ́ẹ̀ ni kò gbọdọ̀ kó wúrà ati fadaka jọ fún ara rẹ̀.#a 1A. Ọba 11:1-8 b 1A. Ọba 10:14-22; 27; 2Kron 1:15; 9:27
18“Nígbà tí ó bá jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀, kí ó gba ìwé òfin yìí lọ́wọ́ àwọn alufaa ọmọ Lefi, kí ó dà á kọ sinu ìwé kan fún ara rẹ̀. 19Kí ẹ̀dà àwọn òfin yìí máa wà pẹlu rẹ̀, kí ó sì máa kà á ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; kí ó lè kọ́ láti bẹ̀rù OLUWA Ọlọrun rẹ̀, nípa pípa gbogbo òfin ati ìlànà wọnyi mọ́, kí ó sì máa tẹ̀lé wọn; 20kí ó má baà rò ninu ara rẹ̀ pé òun ga ju àwọn arakunrin òun lọ, kí ó má baà yipada sí ọ̀tún tabi sí òsì kúrò ninu òfin OLUWA, kí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ lè pẹ́ lórí oyè ní Israẹli.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

DIUTARONOMI 17: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀