DANIẸLI 6:4-10

DANIẸLI 6:4-10 YCE

Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.” Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́, gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun. Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.” Nítorí náà, Dariusi ọba fi ọwọ́ sí òfin náà, ó sì fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́. Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ.