Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego dá ọba lóhùn pé, “Kabiyesi, kò yẹ kí á máa bá ọ jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Bí o bá sọ wá sinu iná, Ọlọrun wa tí à ń sìn lè yọ wá ninu adágún iná, ó sì lè gbà wá lọ́wọ́ ìwọ ọba pàápàá. Ṣugbọn bí kò bá tilẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé a kò ní fi orí balẹ̀, kí á sin ère wúrà tí ó gbé kalẹ̀.”
Inú bá bí Nebukadinesari gidigidi, ojú rẹ̀ yipada sí Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n dá iná, kí ó gbóná ní ìlọ́po meje ju bíí tií máa ń gbóná tẹ́lẹ̀ lọ. Ó tún pàṣẹ pé kí àwọn akọni ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, kí wọ́n sì sọ wọ́n sinu adágún iná. Wọ́n di àwọn mẹtẹẹta pẹlu agbádá, ati aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀, ati fìlà wọn, ati àwọn aṣọ wọn mìíràn, wọ́n sì sọ wọ́n sí ààrin adágún iná tí ń jó. Nítorí bí àṣẹ ọba ti le tó, ati bí adágún iná náà ti gbóná tó, ahọ́n iná tí ń jó bùlàbùlà jó àwọn tí wọ́n gbé Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego sinu rẹ̀ ní àjópa. Nítorí dídì tí wọ́n di Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, wọ́n ṣubú lulẹ̀ sí ààrin iná náà.
Lójijì Nebukadinesari ta gìrì, ó sáré dìde, ó sì bèèrè lọ́wọ́ àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pé, “Ṣebí eniyan mẹta ni a dì, tí a gbé sọ sinu iná?”
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kabiyesi.”
Ó ní, “Ẹ wò ó, eniyan mẹrin ni mo rí yìí, wọ́n wà ní títú sílẹ̀, wọ́n ń rìn káàkiri láàrin iná, iná kò sì jó wọn, Ìrísí ẹni kẹrin dàbí ti ẹ̀dá ọ̀run.”
Nebukadinesari ọba bá lọ sí ẹnu ọ̀nà adágún iná náà, ó kígbe pé, “Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego, ẹ̀yin iranṣẹ Ọlọrun alààyè, ẹ jáde wá!” Wọ́n bá jáde kúrò ninu iná lẹsẹkẹsẹ. Gbogbo àwọn baálẹ̀ ìgbèríko, àwọn olórí, àwọn gomina, ati àwọn ìgbìmọ̀ ọba, kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí i pé iná kò jó àwọn ọkunrin wọnyi, irun orí wọn kò rùn, ẹ̀wù wọn kò yipada, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tilẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.
Nebukadinesari bá dáhùn pé “Ògo ni fún Ọlọrun Ṣadiraki, Meṣaki ati Abedinego tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn iranṣẹ rẹ̀, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e, tí wọn kò ka àṣẹ ọba sí, tí wọ́n fi ẹ̀mí wọn wéwu, dípò kí wọ́n sin ọlọrun mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọrun wọn.