DANIẸLI 2:46-49

DANIẸLI 2:46-49 YCE

Ọba bá wólẹ̀ níwájú Daniẹli, ó fi orí balẹ̀ fún un, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n rúbọ kí wọ́n sì sun turari sí Daniẹli. Ọba sọ fún Daniẹli pé, “Láìsí àní àní, Ọlọrun rẹ ni Ọlọrun àwọn ọlọrun, ati OLUWA àwọn ọba, òun níí fi ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ han eniyan, nítorí pé àṣírí ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ yìí gan-an ni o sọ.” Ọba dá Daniẹli lọ́lá, ó kó oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn ńláńlá fún un, ó sì fi ṣe olórí gbogbo agbègbè Babiloni, ati olórí àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ní Babiloni. Daniẹli gba àṣẹ lọ́wọ́ ọba, ó fi Ṣadiraki, Meṣaki, ati Abedinego ṣe alákòóso àwọn agbègbè Babiloni, ṣugbọn òun wà ní ààfin.