KOLOSE 3:13-16

KOLOSE 3:13-16 YCE

Ẹ ní ìfaradà láàrin ara yín. Ẹ máa dáríjì ara yín bí ẹnikẹ́ni bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnìkejì rẹ̀; gẹ́gẹ́ bí Oluwa ti dáríjì yín bẹ́ẹ̀ gan-an ni kí ẹ̀yin náà máa ṣe sí ara yín. Boríborí gbogbo nǹkan wọnyi, ni pé kí ẹ gbé ìfẹ́ wọ̀. Ìfẹ́ ni ó so àwọn nǹkan yòókù pọ̀, tí ó sì mú wọn pé. Kí alaafia láti ọ̀dọ̀ Kristi máa ṣe alákòóso ọkàn yín; nítorí Ọlọrun pè yín láti jẹ́ ara kan nítorí alaafia yìí, ẹ sì máa ṣọpẹ́. Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.