KOLOSE 1:3-29

KOLOSE 1:3-29 YCE

À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa, Jesu Kristi, nígbà gbogbo tí a bá ń gbadura fun yín. A ti gbúròó igbagbọ yín ninu Kristi Jesu ati ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa. Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí. Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí. A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun. Ati pé kí Ọlọrun fun yín ní agbára gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ ògo rẹ̀, kí ó fun yín ní ìfaradà ninu ohun gbogbo, pẹlu sùúrù ati ayọ̀. Kí ẹ máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Baba wa tí ó kà yín yẹ láti ní ìpín ninu ogún àwọn eniyan Ọlọrun ninu ìmọ́lẹ̀. Baba wa náà ni ó gbà wá lọ́wọ́ agbára òkùnkùn, ó sì mú wa wá sinu ìjọba àyànfẹ́ Ọmọ rẹ̀. Nípasẹ̀ ọmọ rẹ̀ yìí ni a fi ní ìdáǹdè, àní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa. Eniyan kò lè rí Ọlọrun, ṣugbọn ọmọ yìí ni àwòrán rẹ̀, òun ni àkọ́bí ohun gbogbo tí a dá. Nítorí pé, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá ohun gbogbo, lọ́run ati láyé: ati ohun tí a rí, ati ohun tí a kò rí, ìbáà ṣe ìtẹ́ ọba, tabi ìjọba, tabi àwọn alágbára, tabi àwọn aláṣẹ. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni a ti dá gbogbo nǹkan, nítorí tirẹ̀ ni a sì ṣe dá wọn. Ó ti wà ṣiwaju ohun gbogbo. Nípasẹ̀ rẹ̀ ni gbogbo nǹkan sì fi wà létò. Òun ni orí fún ara, tíí ṣe ìjọ. Òun ni ìbẹ̀rẹ̀, àkọ́bí tí a jí dìde láti inú òkú, kí ó lè wà ní ipò tí ó ga ju gbogbo nǹkan lọ. Nítorí ó wu Ọlọrun pé kí ohun tí Ọlọrun tìkararẹ̀ jẹ́ máa gbé inú rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Nípa rẹ̀ ni Ọlọrun ṣe gbogbo nǹkan lọ́kan pẹlu ara rẹ̀, kí alaafia lè dé nípa ikú rẹ̀ lórí agbelebu. Gbogbo nǹkan wá wà ní ìṣọ̀kan, ìbáà ṣe nǹkan ti ayé tabi àwọn nǹkan ti ọ̀run. Ẹ̀yin tí ẹ ti jẹ́ àlejò ati ọ̀tá ninu ọkàn yín nípa iṣẹ́ burúkú yín ni Ọlọrun wá mú wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹlu ara rẹ̀ nípa ikú ọmọ rẹ̀, kí ó lè sọ yín di ẹni tí ó mọ́, tí kò ní àbùkù, tí kò sì ní ẹ̀sùn níwájú rẹ̀, tí ẹ bá dúró ninu igbagbọ, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ dúró gbọningbọnin, tí ẹ kò kúrò ninu ìrètí ìyìn rere tí ẹ ti gbọ́, tí èmi Paulu jẹ́ iranṣẹ rẹ̀, tí a ti waasu rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá ayé. Ní àkókò yìí, mo láyọ̀ ninu ìyà tí mò ń jẹ nítorí yín. Ìyà tí mò ń jẹ ninu ara mi yìí ni èyí tí ó kù tí Kristi ìbá jẹ fún ìjọ, tíí ṣe ara rẹ̀. Nítorí èyí ni mo ṣe di iranṣẹ láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tí Ọlọrun ti fún mi láti ṣe nítorí yín. Ìjìnlẹ̀ àṣírí nìyí, ó ti wà ní ìpamọ́ láti ìgbà àtijọ́ ati láti ìrandíran, ṣugbọn Ọlọrun fihan àwọn eniyan rẹ̀ ní àkókò yìí. Àwọn ni ó wu Ọlọrun pé kí wọ́n mọ ọlá ati ògo àṣírí yìí láàrin àwọn tí kì í ṣe Juu. Àṣírí náà ni pé, Kristi tí ó ń gbé inú yín ni ìrètí ògo. Kristi yìí ni à ń kéde fun yín, tí à ń kìlọ̀ rẹ̀ fún gbogbo eniyan, tí a fi ń kọ́ gbogbo eniyan ní gbogbo ọgbọ́n, kí á lè sọ gbogbo eniyan di pípé ninu Kristi. Ohun tí mò ń ṣiṣẹ́ fún nìyí gẹ́gẹ́ bí agbára tí Ọlọrun fún mi, tí ó ń fún mi ní okun.