AMOSI 5

5
Ìpè sí Ìrònúpìwàdà
1Ẹ fetí sí orin arò tí mò ń kọ le yín lórí, ẹ̀yin ìdílé Israẹli:
2Israẹli, ọdọmọbinrin, ṣubú,
kò ní lè dìde mọ́ lae.
Ó di ìkọ̀sílẹ̀ ní ilẹ̀ rẹ̀,
kò sì sí ẹni tí yóo gbé e dìde.
3OLUWA Ọlọrun ní: “Ninu ẹgbẹrun ọmọ ogun tí ìlú Israẹli kan bá rán jáde, ọgọrun-un péré ni yóo kù. Ninu ọgọrun-un tí ìlú mìíràn bá rán jáde, mẹ́wàá péré ni yóo kù.”
4OLUWA ń sọ fún ilé Israẹli pé: “Ẹ wá mi, kí ẹ sì yè; 5ẹ má lọ sí Bẹtẹli, ẹ má sì wọ Giligali, tabi kí ẹ kọjá lọ sí Beeriṣeba; nítorí a óo kó Giligali lọ sí oko ẹrú, Bẹtẹli yóo sì di asán.”
6Ẹ wá OLUWA, kí ẹ sì yè; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo rọ̀jò iná sórí ilé Josẹfu, ati sí ìlú Bẹtẹli; kò sì ní sí ẹni tí yóo lè pa á. 7Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ẹ̀bi fún aláre, tí ẹ sì tẹ òdodo mọ́lẹ̀.
8Ẹni tí ó dá àwọn ìràwọ̀ Pileiadesi ati Orioni,
tí ó sọ òkùnkùn biribiri di ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀,
òun níí sọ ọ̀sán di òru;
òun ni ó dá omi òkun sórí ilẹ̀,
OLUWA ni orúkọ rẹ̀.
9Òun ni ó ń mú ìparun wá sórí àwọn alágbára,
kí ìparun lè bá ibi ààbò wọn.
10Wọ́n kórìíra ẹni tí ń bá ni wí lẹ́nu ibodè, wọ́n sì kórìíra ẹni tí ń sọ òtítọ́. 11Ẹ̀ ń rẹ́ talaka jẹ, ẹ sì ń fi ipá gba ọkà wọn. Nítòótọ́, ẹ ti fi òkúta tí wọ́n dárà sí kọ́ ilé, ṣugbọn ẹ kò ní gbé inú wọn; ẹ ti ṣe ọgbà àjàrà dáradára, ṣugbọn ẹ kò ní mu ninu ọtí waini ibẹ̀. 12Gbogbo ìwà àìdára yín ni mo mọ̀, mo sì mọ̀ bí ẹ̀ṣẹ̀ yín ti tóbi tó, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fìyà jẹ olódodo, tí ẹ̀ ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀, tí ẹ sì ń du àwọn aláìní ní ẹ̀tọ́ wọn lẹ́nu ibodè. 13Nítorí náà, ẹni tí ó bá gbọ́n yóo dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní irú àkókò yìí, nítorí pé àkókò burúkú ni.
14Ire ni kí ẹ máa wá, kì í ṣe ibi kí ẹ lè wà láàyè; nígbà náà ni OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo wà pẹlu yín, bí ẹ ti jẹ́wọ́ rẹ̀. 15Ẹ kórìíra ibi, kí ẹ sì fẹ́ ire, ẹ jẹ́ kí ìdájọ́ òdodo gbilẹ̀ lẹ́nu ibodè yín; bóyá OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun yóo ṣàánú fún àwọn ọmọ ilé Josẹfu yòókù.
16Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun, àní OLUWA ní: “Ẹkún yóo wà ní gbogbo ìta gbangba, wọn yóo sì máa kọ ‘Háà! Háà!’ nígboro. Wọn yóo pe àwọn àgbẹ̀ pàápàá, ati àwọn tí wọn ń fi ẹkún sísun ṣe iṣẹ́ ṣe, láti wá sọkún àwọn tí wọ́n kú. 17Wọn yóo sọkún ninu gbogbo ọgbà àjàrà yín, nítorí pé n óo gba ààrin yín kọjá. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
18Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń retí ọjọ́ OLUWA, ẹ gbé! Kí ni ẹ fẹ́ fi ọjọ́ OLUWA ṣe? Ọjọ́ òkùnkùn ni, kì í ṣe ọjọ́ ìmọ́lẹ̀. 19Yóo dàbí ìgbà tí eniyan ń sálọ fún kinniun, tí ó pàdé ẹranko beari lọ́nà; tabi tí ó sá wọ ilé rẹ̀, tí ó fọwọ́ ti ògiri, tí ejò tún bù ú jẹ. 20Ṣebí òkùnkùn ni ọjọ́ OLUWA, kì í ṣe ìmọ́lẹ̀! Ọjọ́ ìṣúdudu láìsí ìmọ́lẹ̀ ni.
21Ọlọrun ní, “Mo kórìíra ọjọ́ àsè yín, n kò sì ní inú dídùn sí àwọn àpéjọ yín. 22Bí ẹ tilẹ̀ rú ẹbọ sísun ati ẹbọ ohun jíjẹ yín sí mi, n kò ní gbà wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní fojú rere wo ẹran àbọ́pa tí ẹ mú wá bí ọrẹ ẹbọ alaafia.#Ais 1:11-14 23Ẹ dákẹ́ ariwo orin yín; n kò fẹ́ gbọ́ ohùn orin hapu yín mọ́. 24Ṣugbọn ẹ jẹ́ kí òtítọ́ máa ṣàn bí omi, kí òdodo sì máa ṣàn bí odò tí kò lè gbẹ.
25“Ẹ gbọ́, ilé Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹbọ ati ọrẹ wá fún mi ní gbogbo ogoji ọdún tí ẹ fi wà ninu aṣálẹ̀? 26Ṣugbọn nisinsinyii, ẹ̀ ń sin ère Sakuti, ọba yín, ati Kaiwani, oriṣa ìràwọ̀ yín, ati àwọn ère tí ẹ ṣe fún ara yín. 27Nítorí náà, n óo ko yín lọ sí ìgbèkùn níwájú Damasku.” OLUWA, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọrun àwọn Ọmọ Ogun, ni ó sọ bẹ́ẹ̀.#A. Apo 7:42-43

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AMOSI 5: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀