ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:1-16

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 7:1-16 YCE

Olórí Alufaa bá bi í pé, “Ṣé bẹ́ẹ̀ ni ọ̀ràn náà rí?” Stefanu bá tẹnu bọ̀rọ̀, ó ní, “Ẹ̀yin arakunrin ati baba mi, ẹ gbọ́ ohun tí mo ní sọ. Ọlọrun Ológo farahàn fún baba wa, Abrahamu, nígbà tí ó ṣì wà ní ilẹ̀ Mesopotamia, kí ó tó wá máa gbé ilẹ̀ Kenaani. Ó sọ fún un pé, ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ, láàrin àwọn ẹbí rẹ, kí o lọ sí ilẹ̀ tí èmi yóo fihàn ọ́.’ Ó bá jáde kúrò ní ilẹ̀ Kalidea láti máa gbé Kenaani. Nígbà tí baba rẹ̀ kú, ó kúrò níbẹ̀ láti wá máa gbé ilẹ̀ yìí, níbi tí ẹ̀ ń gbé nisinsinyii. Ní àkókò náà, Ọlọrun kò fún un ní ogún ninu ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ ṣe ẹsẹ̀ bàtà kan, kò ní níbẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ṣe ìlérí láti fún òun ati ọmọ rẹ̀ tí yóo gbẹ̀yìn rẹ̀ ní ilẹ̀ náà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ní ọmọ ní àkókò náà. Ọlọrun sọ fún un pé, ‘Àwọn ọmọ rẹ yóo jẹ́ àlejò ní ilẹ̀ àjèjì. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo lò wọ́n bí ẹrú, wọn óo pọ́n wọn lójú fún irinwo (400) ọdún. Ṣugbọn orílẹ̀-èdè tí ó lò wọ́n bí ẹrú ni Èmi yóo dá lẹ́jọ́. Lẹ́yìn náà wọn yóo jáde kúrò ní ilẹ̀ àjèjì náà, wọn óo sì sìn mí ní ilẹ̀ yìí.’ Ọlọrun wá bá a dá majẹmu, ó fi ilà kíkọ ṣe àmì majẹmu náà. Nígbà tí ó bí Isaaki, ó kọ ọ́ nílà ní ọjọ́ kẹjọ. Isaaki bí Jakọbu. Jakọbu bí àwọn baba-ńlá wa mejila. “Àwọn baba-ńlá wa jowú Josẹfu, wọ́n tà á lẹ́rú sí ilẹ̀ Ijipti. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. Ọlọrun yọ ọ́ kúrò ninu gbogbo ìpọ́njú tí ó rí. Nígbà tí ó yọ siwaju Farao, ọba Ijipti, Ọlọrun fún un lọ́gbọ́n, ó sì jẹ́ kí ó rí ojú àánú ọba Ijipti. Farao bá fi jẹ gomina lórí gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati lórí ààfin ọba. Nígbà tí ó yá, ìyàn mú ní gbogbo ilẹ̀ Ijipti ati ní ilẹ̀ Kenaani. Eléyìí mú ìṣòro pupọ wá. Àwọn eniyan wa kò bá rí oúnjẹ jẹ. Nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé oúnjẹ wà ní Ijipti, ó kọ́kọ́ rán àwọn baba wa lọ. Ní ẹẹkeji ni àwọn arakunrin rẹ̀ tó mọ ẹni tí Josẹfu jẹ́. A sì fi ìdílé Josẹfu han Farao. Josẹfu bá ranṣẹ láti pe Jakọbu baba rẹ̀ wá ati gbogbo àwọn ẹbí rẹ̀. Wọ́n jẹ́ eniyan marunlelaadọrin (75). Jakọbu bá lọ sí Ijipti. Níbẹ̀ ni ó kú sí, òun ati àwọn baba wa náà. Wọ́n gbé òkú wọn lọ sí Ṣekemu, wọ́n sin wọ́n sinu ibojì tí Abrahamu fowó rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori ní Ṣekemu.