ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:19-21

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 5:19-21 YCE

Nígbà tí ó di òru, angẹli Oluwa ṣí ìlẹ̀kùn ilé-ẹ̀wọ̀n, ó sìn wọ́n jáde, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ lọ dúró ninu Tẹmpili kí ẹ sọ gbogbo ọ̀rọ̀ ìyè yìí fún àwọn eniyan.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n wọ inú Tẹmpili lọ nígbà tí ojúmọ́ mọ́, wọ́n bá ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́. Nígbà tí Olórí Alufaa dé pẹlu àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, ó pe ìgbìmọ̀ ati gbogbo àwọn àgbààgbà láàrin àwọn ọmọ Israẹli jọ. Wọ́n bá ranṣẹ lọ sí inú ẹ̀wọ̀n kí wọn lọ mú àwọn aposteli náà wá.