ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:14-47

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 2:14-47 YCE

Peteru wá dìde dúró pẹlu àwọn aposteli mọkanla, ó sọ̀rọ̀ sókè, ó ní, “Ẹ̀yin ará, ẹ̀yin Juu, ati gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yìí ye yín, kí ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Àwọn yìí kò mutí yó bí ẹ ti rò, nítorí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ di agogo mẹsan-an òwúrọ̀ ni. Ṣugbọn ohun tí Joẹli, wolii Ọlọrun ti sọ wá ṣẹ lónìí, tí ó wí pé, ‘Ọlọrun sọ pé, “Nígbà tí ó bá di àkókò ìkẹyìn, n óo tú Ẹ̀mí mi jáde sórí gbogbo eniyan. Àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin yóo sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ọdọmọkunrin yín yóo rí ìran, àwọn àgbà yín yóo sì lá àlá. Àní, ní àkókò náà, n óo tú Ẹ̀mí mi sórí àwọn ẹrukunrin mi ati sí orí àwọn ẹrubinrin mi, àwọn náà yóo sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. N óo fi ohun ìyanu hàn lókè ọ̀run, ati ohun abàmì lórí ilẹ̀ ayé; ẹ̀jẹ̀, ati iná, ìkùukùu ati èéfín. Oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá yóo di ẹ̀jẹ̀, kí ó tó di ọjọ́ ńlá tí ó lókìkí, ọjọ́ Oluwa. Ní ọjọ́ náà gbogbo ẹni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a óo gbà là.” ’ “Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á. Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀. Nítorí Dafidi sọ nípa rẹ̀ pé, ‘Mo rí Oluwa níwájú mi nígbà gbogbo, ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi nítorí náà ohunkohun kò lè dà mí láàmú. Nítorí náà inú mi dùn, mo bú sẹ́rìn-ín. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé eniyan ẹlẹ́ran-ara ni mí, sibẹ n óo gbé ìgbé-ayé mi pẹlu ìrètí; nítorí o kò ní fi ọkàn mi sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú; bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ rí ìdíbàjẹ́. O ti fi ọ̀nà ìyè hàn mí, O óo sì fi ayọ̀ kún ọkàn mi níwájú rẹ.’ “Ẹ̀yin ará, mo sọ fun yín láìṣe àní-àní pé Dafidi baba-ńlá wa kú, a sì sin ín; ibojì rẹ̀ wà níhìn-ín títí di òní. Ṣugbọn nítorí ó jẹ́ aríran, ó sì mọ̀ pé Ọlọrun ti búra fún òun pé ọ̀kan ninu ọmọ tí òun óo bí ni yóo jókòó lórí ìtẹ́ òun, ó ti rí i tẹ́lẹ̀ pé Mesaya yóo jí dìde kúrò ninu òkú. Ìdí nìyí tí ó fi sọ pé, ‘A kò fi í sílẹ̀ ní ibùgbé àwọn òkú; bẹ́ẹ̀ ni ẹran-ara rẹ̀ kò díbàjẹ́.’ Jesu yìí ni Ọlọrun jí dìde. Gbogbo àwa yìí sì ni ẹlẹ́rìí. Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí. Nítorí Dafidi kò gòkè lọ sí ọ̀run. Ohun tí Dafidi sọ ni pé, ‘Oluwa wí fún oluwa mi pé: Jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi títí n óo fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di tìmùtìmù ìtìsẹ̀ rẹ.’ “Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!” Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?” Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.” Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.” A ṣe ìrìbọmi fún àwọn tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà. Ní ọjọ́ náà àwọn ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a kà kún ọmọ ìjọ. Wọ́n ń fi tọkàntọkàn kọ́ ẹ̀kọ́ tí àwọn aposteli ń kọ́ wọn; wọ́n wà ní ìrẹ́pọ̀, wọ́n jọ ń jẹun; wọ́n jọ ń gbadura. Ẹ̀rù àwọn onigbagbọ wá ń ba gbogbo eniyan. Ọpọlọpọ ni iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì tí a ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe. Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀. Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí. Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan. Wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan ni ó fẹ́ràn wọn. Lojoojumọ ni àwọn tí wọ́n rí ìgbàlà ń dara pọ̀ mọ́ wọn.