ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1:12-24

ÌṢE ÀWỌN APOSTELI 1:12-24 YCE

Wọ́n pada sí Jerusalẹmu láti orí òkè tí à ń pè ní Òkè Olifi. Òkè náà súnmọ́ Jerusalẹmu, kò tó ibùsọ̀ kan sí ìlú. Nígbà tí wọ́n wọ inú ilé, wọ́n lọ sí iyàrá òkè níbi tí wọn ń gbé. Àwọn tí wọ́n jọ ń gbé ni Peteru, Johanu, Jakọbu, Anderu, Filipi, Tomasi, Batolomiu, Matiu, Jakọbu ọmọ Alfeu, Simoni ti ẹgbẹ́ Seloti ati Judasi ọmọ Jakọbu. Gbogbo wọn ń fi ọkàn kan gbadura nígbà gbogbo pẹlu àwọn obinrin ati Maria ìyá Jesu ati àwọn arakunrin Jesu. Ní ọjọ́ kan, Peteru dìde láàrin àwọn arakunrin tí wọ́n tó ọgọfa eniyan, ó ní, “Ẹ̀yin ará, dandan ni pé kí ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ sọ ninu Ìwé Mímọ́ láti ẹnu Dafidi ṣẹ, nípa ọ̀rọ̀ Judasi tí ó ṣe amọ̀nà àwọn tí ó mú Jesu. Nítorí ọ̀kan ninu wa ni, ó sì ní ìpín ninu iṣẹ́ yìí.” (Ó ra ilẹ̀ kan pẹlu owó tí ó gbà fún ìwà burúkú rẹ̀, ni ó bá ṣubú lulẹ̀, ikùn rẹ̀ sì bẹ́, gbogbo ìfun rẹ̀ bá tú jáde. Gbogbo àwọn eniyan tí ó ń gbé Jerusalẹmu ni ó mọ̀ nípa èyí. Wọ́n bá ń pe ilẹ̀ náà ní “Akelidama” ní èdè wọn. Ìtumọ̀ èyí ni “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀.”) “Ọ̀rọ̀ náà rí bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu Ìwé Orin Dafidi pé, ‘Kí ibùgbé rẹ̀ di ahoro, kí ẹnikẹ́ni má gbé ibẹ̀.’ Ati pé, ‘Kí á fi ipò rẹ̀ fún ẹlòmíràn.’ “Nítorí náà, ẹ̀tọ́ ni kí á yan ẹnìkan ninu àwọn tí ó ti wà pẹlu wa ní gbogbo àkókò tí Jesu Oluwa ti ń wọlé, tí ó ń jáde pẹlu wa, láti àkókò tí Johanu ti ń ṣe ìrìbọmi títí di ọjọ́ tí a fi mú Jesu kúrò lọ́dọ̀ wa, kí olúwarẹ̀ lè jẹ́ ẹlẹ́rìí ajinde Jesu, kí ó sì di ọ̀kan ninu wa.” Wọ́n bá gbé ẹni meji siwaju: Josẹfu tí à ń pè ní Basaba, tí ó tún ń jẹ́ Jusitu, ati Matiasi. Wọ́n gbadura pé, “Ìwọ Oluwa, Olùmọ̀ràn gbogbo eniyan, fi ẹni tí o bá yàn ninu àwọn mejeeji yìí hàn