TIMOTI KEJI 2:20-21

TIMOTI KEJI 2:20-21 YCE

Kì í ṣe àwọn ohun èèlò wúrà ati ti fadaka nìkan ni ó ń wà ninu ilé ńlá. Àwọn nǹkan tí wọ́n fi igi ati amọ̀ ṣe wà níbẹ̀ pẹlu. À ń lo àwọn kan fún nǹkan pataki; à ń lo àwọn mìíràn fún ohun tí kò ṣe pataki tóbẹ́ẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wẹ ara rẹ̀ mọ́ kúrò ninu àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ yóo di ohun èèlò tí ó níye lórí, tí a yà sọ́tọ̀, tí ó wúlò fún baálé ilé. Yóo di ẹni tí ó ṣetán láti ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere.