TIMOTI KEJI 1:2-4

TIMOTI KEJI 1:2-4 YCE

Sí Timoti, àyànfẹ́ ọmọ mi. Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu, Oluwa wa, wà pẹlu rẹ. Nígbà tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura mi tọ̀sán-tòru, èmi a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí mò ń sìn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba-ńlá mi ti ṣe. Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún.