Ẹ̀yin ará, ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nígbà gbogbo nítorí yín. Ó tọ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé igbagbọ yín ń tóbi sí i, ìfẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan yín sí ara yín sì ń pọ̀ sí i. Àwa fúnra wa ń fọ́nnu nípa yín láàrin àwọn ìjọ Ọlọrun. À ń ròyìn ìfaradà ati igbagbọ yín ninu gbogbo inúnibíni ati ìpọ́njú tí ẹ̀ ń faradà. Ìfaradà yín jẹ́ ẹ̀rí ìdájọ́ òdodo Ọlọrun láti kà yín yẹ fún ìjọba rẹ̀ tí ẹ̀ ń tìtorí rẹ̀ jìyà. Nítorí ó tọ́ lójú Ọlọrun láti fi ìpọ́njú san ẹ̀san fún àwọn tí wọn ń pọn yín lójú, ati láti fún ẹ̀yin tí wọn ń pọ́n lójú, ati àwa náà ní ìsinmi, nígbà tí Oluwa wa, Jesu, bá farahàn láti ọ̀run ninu ọwọ́ iná pẹlu àwọn angẹli tí wọ́n jẹ́ alágbára.
Kà TẸSALONIKA KEJI 1
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: TẸSALONIKA KEJI 1:3-7
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò