ÀWỌN ỌBA KEJI 23

23
Josaya pa Ìbọ̀rìṣà Run
(2Kron 34:3-7, 29-33)
1Josaya bá pe ìpàdé gbogbo àwọn olórí Juda ati Jerusalẹmu. 2Gbogbo wọn lọ sí ilé OLUWA pẹlu àwọn alufaa ati àwọn wolii ati gbogbo àwọn eniyan, àtọmọdé àtàgbà wọn. Ọba bá ka ìwé majẹmu tí wọ́n rí ninu ilé OLUWA sí etígbọ̀ọ́ wọn. 3Ọba dúró sí ààyè rẹ̀, lẹ́bàá òpó, ó bá OLUWA dá majẹmu pé òun óo máa rìn ní ọ̀nà OLUWA ati láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ ati láti mú gbogbo ohun tí ó wà ninu Ìwé náà ṣẹ. Gbogbo àwọn eniyan sì ṣe ìlérí láti pa majẹmu náà mọ́.
4Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli. 5Gbogbo àwọn alufaa tí àwọn ọba Juda ti yàn láti máa rúbọ lórí pẹpẹ oriṣa ní àwọn ìlú Juda ati ní agbègbè Jerusalẹmu ni Josaya dá dúró, ati gbogbo àwọn tí wọn ń rúbọ sí oriṣa Baali, sí oòrùn, òṣùpá, àwọn ìràwọ̀, ati àwọn nǹkan tí wọ́n wà ní òfuurufú. 6Ó kó gbogbo àwọn ère oriṣa Aṣera tí ó wà ninu ilé OLUWA lọ sí àfonífojì Kidironi lẹ́yìn Jerusalẹmu. Ó sun wọ́n níná níbẹ̀, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì fọ́n eérú wọn ká sórí ibojì àwọn eniyan. 7Ó wó gbogbo ibi tí àwọn tí wọ́n máa ń ṣe panṣaga fún ìsìn Aṣera ń gbé létí ilé OLUWA lulẹ̀, níbi tí àwọn obinrin ti máa ń hun aṣọ fún ìsìn Aṣera. 8Gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà káàkiri ilẹ̀ Juda ni ó mú wá sí Jerusalẹmu, ó sì ba gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí wọ́n ti ń rúbọ jẹ́. Ó wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní ẹnubodè, tí Joṣua, baálẹ̀ ìlú kọ́, tí ó wà ní apá òsì, bí eniyan bá ti fẹ́ wọ ìlú. 9Kò gba àwọn alufaa náà láàyè láti ṣiṣẹ́ ninu ilé OLUWA, ṣugbọn wọ́n lè jẹ ninu àkàrà tí wọn kò fi ìwúkàrà ṣe, tí ó jẹ́ ti àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn.#2A. Ọba 21:3; 2Kron 33:3
10Josaya Ọba wó ilé oriṣa Tofeti tí ó wà ní àfonífojì Hinomu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè fi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin rẹ̀ rúbọ sí oriṣa Moleki mọ́.#a Jer 7:31; 19:1-6; 32:35 b Lef 18:21 11Ó tú gbogbo ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn, ní ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, lẹ́bàá yàrá Natani Meleki, ìwẹ̀fà tí ó wà ní agbègbè ilé OLUWA; ó sì dáná sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun tí wọ́n yà sọ́tọ̀ fún ìsìn oòrùn. 12Ó wó àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí àwọn ọba Juda kọ́ sórí ilé Ahasi ninu ààfin lulẹ̀, pẹlu àwọn pẹpẹ ìrúbọ tí Manase kọ́ sinu àwọn àgbàlá meji tí ó wà ninu ilé OLUWA. Ó fọ́ gbogbo wọn túútúú, ó sì kó wọn dà sí àfonífojì Kidironi.#2A. Ọba 21:5; 2Kron 33:5 13Josaya wó gbogbo ibi gíga tí wọn tún ń pè ní òkè ìdíbàjẹ́, tí Solomoni kọ́ sí apá ìhà ìlà oòrùn Jerusalẹmu, ní ìhà gúsù Òkè Olifi, fún àwọn oriṣa Aṣitoreti, ohun ìríra àwọn ará Sidoni, ati Kemoṣi, ohun ìríra àwọn ará Moabu, ati fún Milikomu, ohun ìríra àwọn ará Amoni. 14Josaya ọba fọ́ àwọn òpó òkúta túútúú, ó gé àwọn ère oriṣa Aṣera, ó sì kó egungun eniyan sí ibi tí wọ́n ti hú wọn jáde.#1A. Ọba 11:7
15Josaya wó ilé oriṣa tí Jeroboamu ọba, ọmọ Nebati, ẹni tí ó mú Israẹli ṣẹ̀, kọ́ sí Bẹtẹli. Josaya wó pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà níbẹ̀, ó fọ́ òkúta rẹ̀ túútúú, ó lọ̀ wọ́n lúbúlúbú, ó sì jó ère Aṣera pẹlu.#1A. Ọba 12:33 16Bí Josaya ti yí ojú pada, ó rí àwọn ibojì kan lórí òkè. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn egungun inú wọn jáde, kí wọ́n sì jó wọn lórí pẹpẹ ìrúbọ náà; ó sì fi bẹ́ẹ̀ sọ pẹpẹ ìrúbọ náà di ìbàjẹ́, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Ọlọrun ti sọ. Nígbà tí Josaya ọba rí ibojì wolii tí ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ náà,#1A. Ọba 13:2 17ó bèèrè pé, “Ọ̀wọ̀n ibojì ta ni mò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yìí?”
Àwọn tí wọ́n wà ní Bẹtẹli sì dáhùn pé, “Ibojì wolii tí ó wá láti Juda tí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ohun tí ò ń ṣe sí pẹpẹ ìrúbọ yìí ni.”#1A. Ọba 13:30-32
18Josaya bá pàṣẹ pé kí wọ́n fi sílẹ̀ bí ó ti wà, kí wọ́n má ṣe kó egungun rẹ̀.
Nítorí náà, wọn kò kó egungun rẹ̀ ati egungun wolii tí ó wá láti Samaria.
19Ní gbogbo àwọn ìlú Israẹli ni Josaya ti wó àwọn ilé oriṣa tí àwọn ọba Israẹli kọ́ tí ó bí OLUWA ninu. Bí ó ti ṣe pẹpẹ ìrúbọ tí ó wà ní Bẹtẹli ni ó ṣe àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. 20Ó pa gbogbo àwọn alufaa ibi ìrúbọ lórí pẹpẹ ìrúbọ wọn, ó sì jó egungun eniyan lórí gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ náà. Lẹ́yìn náà, ó pada sí Jerusalẹmu.
Josaya Ọba ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá
(2Kron 35:1-19)
21Josaya pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA Ọlọrun wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu ìwé majẹmu; 22nítorí pé wọn kò ti ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá mọ́ láti àkókò àwọn onídàájọ́ ati ti àwọn ọba Israẹli ati Juda. 23Ṣugbọn ní ọdún kejidinlogun tí Josaya ti jọba ni àwọn eniyan ṣe Àjọ̀dún Àjọ Ìrékọjá fún ògo OLUWA ní Jerusalẹmu.
Àwọn Àtúnṣe Mìíràn tí Josaya Ṣe
24Josaya ọba lé gbogbo àwọn abókùúsọ̀rọ̀ ati àwọn oṣó jáde kúrò ní Jerusalẹmu, ó sì kó àwọn ère, àwọn oriṣa, ati gbogbo ohun ìbọ̀rìṣà kúrò ní Jerusalẹmu ati ilẹ̀ Juda, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu òfin tí ó wà ninu ìwé tí Hilikaya olórí alufaa rí ninu ilé OLUWA. 25Ṣáájú Josaya ati lẹ́yìn rẹ̀, kò sí ọba kankan tí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀, gbogbo ẹ̀mí rẹ̀ ati gbogbo agbára rẹ̀ sin Ọlọrun, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ninu gbogbo òfin Mose.
26Ṣugbọn sibẹsibẹ ibinu gbígbóná OLUWA tí ó ti ru sókè sí Juda nítorí ìwà burúkú Manase kò rọlẹ̀. 27OLUWA sọ pé, “N óo ṣe ohun tí mo ṣe sí Israẹli sí Juda, n óo pa àwọn eniyan Juda run, n óo sì kọ Jerusalẹmu, ìlú tí mo yàn sílẹ̀, ati ilé OLUWA tí mo yàn fún ìsìn mi.”
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Josaya
(2Kron 35:20–36:1)
28Gbogbo nǹkan yòókù tí Josaya ṣe ni a kọ sinu Ìwé Ìtàn Àwọn Ọba Juda. 29Ní àkókò tí Josaya jọba ni Neko, ọba Ijipti kó ogun rẹ̀ wá sí etí odò Yufurate láti ran ọba Asiria lọ́wọ́. Josaya pinnu láti dá ogun Ijipti pada ní Megido, ṣugbọn ó kú lójú ogun náà. 30Àwọn olórí ogun rẹ̀ gbé òkú rẹ̀ sinu kẹ̀kẹ́ ogun kan láti Megido wọn gbé e wá sí Jerusalẹmu, wọ́n sì sin ín sinu ibojì rẹ̀.
Àwọn eniyan Juda sì fi òróró yan Jehoahasi ọmọ rẹ̀ ní ọba.
Jehoahasi, Ọba Juda
(2Kron 36:2-4)
31Ẹni ọdún mẹtalelogun ni Jehoahasi nígbà tí ó jọba ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún oṣù mẹta. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Hamutali, ọmọ Jeremaya, ará Libina. 32Òun náà ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀. 33Neko ọba Ijipti mú Jehoahasi ní ìgbèkùn ní Ribila ní ilẹ̀ Hamati, kí ó má baà jọba lórí Jerusalẹmu mọ́. Ó sì mú kí Juda san ọgọrun-un (100) ìwọ̀n talẹnti fadaka ati ìwọ̀n talẹnti wúrà kan bí ìṣákọ́lẹ̀. 34Neko sì fi Eliakimu, ọmọ Josaya, jọba dípò rẹ̀, ṣugbọn ó yí orúkọ rẹ̀ pada sí Jehoiakimu. Neko mú Jehoahasi lọ sí Ijipti, ibẹ̀ ni ó sì kú sí.#Jer 22:11-12
Jehoiakimu Ọba Juda
(2Kron 36:5-8)
35Jehoiakimu ọba gba owó orí lọ́wọ́ àwọn eniyan gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ wọn ti pọ̀ tó, láti rí owó san ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba Ijipti gẹ́gẹ́ bí ó ti pa á láṣẹ fún un.
36Jehoiakimu jẹ́ ẹni ọdún mẹẹdọgbọn nígbà tí ó jọba, ó sì jọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọkanla. Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Sebida, ọmọ Pedaaya, láti ìlú Ruma. 37Ó ṣe ohun tí ó burú lójú OLUWA, ó tẹ̀lé ìwà ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀.#Jer 22:18-19; 26:1-6; 35:1-19

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

ÀWỌN ỌBA KEJI 23: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀