KỌRINTI KEJI 5:15-17

KỌRINTI KEJI 5:15-17 YCE

Ìdí tí Kristi fi kú fún gbogbo eniyan ni pé kí àwọn tí ó wà láàyè má ṣe wà láàyè fún ara wọn, ṣugbọn kí wọ́n lè wà láàyè fún ẹni tí ó kú fún wa, tí Ọlọrun sì jí dìde. Àyọrísí gbogbo èyí ni pé, láti ìgbà yìí lọ, àwa kò tún ní wo ẹnikẹ́ni ní ìwò ti ẹ̀dá mọ́. Nígbà kan ìwò ti ẹ̀dá ni à ń wo Kristi, ṣugbọn a kò tún wò ó bẹ́ẹ̀ mọ́. Èyí ni pé nígbà tí ẹnikẹ́ni bá wà ninu Kristi, ó di ẹ̀dá titun. Ohun àtijọ́ ti kọjá lọ. Ìgbé-ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀ sì di titun.