Èmi Paulu fi ìrẹ̀lẹ̀ Kristi ati àánú rẹ̀ bẹ̀ yín, èmi tí ẹ̀ ń sọ pé nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín mo jẹ́ eniyan jẹ́jẹ́, ṣugbọn nígbà tí mo bá kúrò lọ́dọ̀ yín mo di ògbójú si yín. Mo bẹ̀ yín, ẹ má ṣe jẹ́ kí n wá sọ́dọ̀ yín pẹlu ìgbójú, nítorí ó dá mi lójú pé mo lè ko àwọn kan, tí wọ́n sọ pé à ń hùwà bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa lójú. Nítorí à ń gbé ìgbé-ayé wa ninu àìlera ti ara, ṣugbọn a kò jagun gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ó ń wá ire ara wa, nítorí àwọn ohun-ìjà wa kì í ṣe ti ayé, agbára Ọlọrun ni, tí a lè fi wó ìlú olódi. À ń bi gbogbo iyàn jíjà lórí èké ṣubú, ati gbogbo ìdínà tí ó bá gbórí sókè tí ó lòdì sí ìmọ̀ Ọlọrun. A mú gbogbo èrò ọkàn ní ìgbèkùn kí ó lè gbọ́ràn sí Kristi lẹ́nu. A sì ti múra tán láti jẹ gbogbo aláìgbọràn níyà, nígbà tí ẹ bá ti fi ara yín sábẹ́ wa.
Kà KỌRINTI KEJI 10
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: KỌRINTI KEJI 10:1-6
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò