KRONIKA KEJI 5
5
1Nígbà tí Solomoni ọba parí gbogbo iṣẹ́ ilé OLUWA, ó kó gbogbo nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sí mímọ́ wá sinu ilé Ọlọrun: àwọn nǹkan bíi fadaka, wúrà, ati gbogbo ohun èlò, ó pa wọ́n mọ́ ninu àwọn ilé ìṣúra tí wọ́n wà níbẹ̀.#2Sam 8:11; 1Kron 18:11
Gbígbé Àpótí Ẹ̀rí Wá sinu Tẹmpili
(1A. Ọba 8:1-9)
2Lẹ́yìn náà, Solomoni pe gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli jọ, àwọn olórí ẹ̀yà, ati àwọn baálé baálé ní ìdílé Israẹli ati ti Jerusalẹmu, láti gbé àpótí majẹmu OLUWA láti Sioni, ìlú Dafidi, wá sinu tẹmpili. 3Gbogbo wọn péjọ sọ́dọ̀ ọba ní àkókò àjọ̀dún, ní oṣù keje. 4Nígbà tí àwọn àgbààgbà péjọ tán, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà. 5Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí náà wá pẹlu àgọ́ àjọ, ati gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà ninu àgọ́ àjọ náà. 6Solomoni ọba ati gbogbo ìjọ Israẹli dúró níwájú àpótí majẹmu, wọ́n ń fi ọpọlọpọ aguntan ati ọpọlọpọ mààlúù tí kò níye rúbọ. 7Àwọn alufaa gbé àpótí majẹmu OLUWA wá sí ààyè rẹ̀ ninu tẹmpili ní ibi mímọ́ jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ àwọn ìyẹ́ kerubu. 8Àwọn kerubu na àwọn ìyẹ́ wọn sórí ibi tí àpótí náà wà tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n bo àpótí náà ati àwọn òpó rẹ̀. 9Àwọn ọ̀pá náà gùn tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi lè rí orí wọn láti ibi mímọ́ jùlọ, ṣugbọn wọn kò lè rí wọn láti ìta. Wọ́n wà níbẹ̀ títí di òní olónìí. 10Ohun kan ṣoṣo tí ó wà ninu àpótí náà ni tabili meji tí Mose kó sibẹ ní òkè Horebu, níbi tí Ọlọrun ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu nígbà tí wọ́n jáde kúrò ní Ijipti.#2Sam 6:12-15; 1Kron 15:25-28 #Diut 10:5
Ògo OLUWA
11Gbogbo àwọn alufaa jáde wá láti ibi mímọ́, (nítorí gbogbo àwọn alufaa tí wọ́n wà níbẹ̀ ti ya ara wọn sí mímọ́ láìbèèrè ìpín tí olukuluku wà. 12Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni, àwọn ọmọkunrin wọn ati àwọn ìbátan wọn dúró ní apá ìhà ìlà oòrùn pẹpẹ. Wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, wọ́n ń fi ìlù, hapu ati dùùrù kọrin; pẹlu ọgọfa alufaa tí wọ́n ń fi fèrè kọrin, 13àwọn onífèrè ati àwọn akọrin pa ohùn pọ̀ wọ́n ń kọ orin ìyìn ati orin ọpẹ́ sí OLUWA). Wọ́n ń fi fèrè ati ìlù ati àwọn ohun èlò orin mìíràn kọrin ìyìn sí OLUWA pé:
“OLUWA ṣeun,
ìfẹ́ ńlá Rẹ̀ kò lópin.”
Ìkùukùu kún inú tẹmpili OLUWA, 14tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn alufaa kò fi lè ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn, nítorí ògo OLUWA tí ó kún ilé Ọlọrun.#1Kron 16:34; 2Kron 7:3; Ẹsr 3:11; O. Daf 100:5; 106:1; 107:1; 118:1; 136:1; Jer 33:11 #Eks 40:34-35
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
KRONIKA KEJI 5: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010