KRONIKA KEJI 33

33
Manase, Ọba Juda
(2A. Ọba 21:1-9)
1Ọmọ ọdún mejila ni Manase nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè ní Jerusalẹmu fún ọdún marundinlọgọta. 2Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA. Gbogbo nǹkan ẹ̀gbin tí àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA lé jáde fún àwọn ọmọ Israẹli máa ń ṣe ni òun náà ṣe. 3Gbogbo ibi ìrúbọ tí Hesekaya, baba rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ó tún kọ́. Ó tẹ́ pẹpẹ fún Baali, ó sì ri àwọn òpó fún Aṣera. Ó ń bọ àwọn ìràwọ̀, ó sì ń sìn wọ́n. 4Ó tẹ́ pẹpẹ oriṣa sinu ilé OLUWA, ilé tí OLUWA ti sọ nípa rẹ̀ pé, “Ní Jerusalẹmu ni ibi ìjọ́sìn tí orúkọ mi yóo wà, tí ẹ óo ti máa sìn mí títí lae.” 5Ó tẹ́ pẹpẹ sinu gbọ̀ngàn meji tí ó wà ninu tẹmpili, wọ́n sì ń bọ àwọn ìràwọ̀ ati gbogbo ohun tí ó wà lójú ọ̀run níbẹ̀. 6Ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ sísun ní àfonífojì ọmọ Hinomu. Ó ń lo àfọ̀ṣẹ, ó ń woṣẹ́, a sì máa lọ sọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Ó dẹ́ṣẹ̀ sí OLUWA tóbẹ́ẹ̀ tí inú OLUWA fi bẹ̀rẹ̀ sí ru. 7Ó gbé ère oriṣa tí ó gbẹ́ wá sí ilé Ọlọrun, ilé tí Ọlọrun ti sọ nípa rẹ̀ fún Dafidi ati Solomoni, ọmọ rẹ̀ pé, “Ninu ilé yìí ati ní Jerusalẹmu tí mo ti yàn láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila ni wọn yóo ti máa sìn mí. 8Bí àwọn ọmọ Israẹli bá pa òfin mi mọ́, tí wọ́n sì tẹ̀lé gbogbo ìlànà ati ìdájọ́ mi tí mo fún wọn láti ọwọ́ Mose, n kò ní ṣí wọn nídìí mọ́ lórí ilẹ̀ tí mo ti yàn fún àwọn baba wọn.” 9Manase ṣi àwọn ará Juda ati Jerusalẹmu lọ́nà, tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi ṣe burúkú ju àwọn orílẹ̀-èdè tí OLUWA parun fún Israẹli lọ.#Jer 15:4 #1Kron 6:6 #1A. Ọba 9:3-5; 2Kron 7:12-18
Manase Ronupiwada
10OLUWA kìlọ̀ fún Manase ati gbogbo àwọn eniyan rẹ̀, ṣugbọn wọ́n kọ̀, wọn kò gbọ́. 11Nítorí náà, OLUWA mú kí ọ̀gágun ilẹ̀ Asiria wá ṣẹgun Juda, wọ́n fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà de Manase, wọ́n fi ìwọ̀ mú un, wọ́n sì fà á lọ sí Babiloni. 12Nígbà tí ó wà ninu ìpọ́njú ó wá ojurere OLUWA Ọlọrun, ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ patapata níwájú Ọlọrun àwọn baba rẹ̀. 13Ó gbadura sí OLUWA, OLUWA gbọ́ adura rẹ̀, ó sì mú un pada wá sórí ìtẹ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu. Ó wá mọ̀ nígbà náà pé OLUWA ni Ọlọrun.
14Lẹ́yìn náà ó mọ odi ìta sí ìlú Dafidi, ní apá ìwọ̀ oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, ati sí ẹnubodè ẹja; ó mọ ọ́n tí ó ga yípo Ofeli. Ó kó àwọn ọ̀gágun sinu àwọn ìlú olódi ní Juda. 15Ó kó àwọn oriṣa ati àwọn ère kúrò ninu ilé OLUWA, ati gbogbo ojúbọ oriṣa tí ó kọ́ sórí òkè níbi tí ilé OLUWA wà, ati àwọn tí wọ́n kọ́ káàkiri gbogbo ìlú Jerusalẹmu. Ó da gbogbo wọn sẹ́yìn odi ìlú. 16Ó tún pẹpẹ OLUWA tẹ́ sí ipò rẹ̀, ó rú ẹbọ alaafia ati ẹbọ ọpẹ́ lórí rẹ̀, ó sì pàṣẹ fún àwọn eniyan Juda pé kí wọ́n máa sin OLUWA Ọlọrun Israẹli. 17Sibẹsibẹ àwọn eniyan ṣì ń rúbọ ní àwọn ibi ìrúbọ, ṣugbọn OLUWA Ọlọrun wọn ni wọ́n ń rúbọ sí.
Ìgbẹ̀yìn Ìjọba Manase
(2A. Ọba 21:17-18)
18Àkọsílẹ̀ àwọn nǹkan yòókù tí Manase ṣe, ati adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati àwọn ọ̀rọ̀ tí aríran sọ fún un ní orúkọ OLUWA, Ọlọrun Israẹli, gbogbo rẹ̀ wà ninu ìwé ìtàn àwọn ọba Israẹli. 19Adura rẹ̀ sí Ọlọrun, ati bí Ọlọrun ṣe dá a lóhùn, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ati aiṣododo rẹ̀, wà ninu ìwé Ìtàn Àwọn Aríran. Bẹ́ẹ̀ náà ni gbogbo ibi tí ó kọ́ pẹpẹ ìrúbọ rẹ̀ sí, àwọn ère tí ó gbẹ́ fún Aṣera, ati àwọn ère tí ó ń sìn kí ó tó ronupiwada. 20Nígbà tí ó kú, wọ́n sin ín sí ààfin rẹ̀. Amoni, ọmọ rẹ̀ sì jọba lẹ́yìn rẹ̀.
Amoni, Ọba Juda
(2A. Ọba 21:19-26)
21Ọmọ ọdún mejilelogun ni Amoni nígbà tí ó jọba, ó sì wà lórí oyè fún ọdún meji ní Jerusalẹmu. 22Ó ṣe nǹkan burúkú lójú OLUWA, bíi Manase, baba rẹ̀, ó rúbọ sí gbogbo oriṣa tí baba rẹ̀ ṣe, ó sì ń bọ wọ́n. 23Kò fi ìgbà kankan ronupiwada bí baba rẹ̀ ti ṣe níwájú OLUWA. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀ṣẹ̀ ni ó ń dá kún ẹ̀ṣẹ̀.
24Nígbà tí ó yá, àwọn ọ̀gágun rẹ̀ dìtẹ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì pa á ní ààfin rẹ̀. 25Ṣugbọn gbogbo àwọn ará ilẹ̀ Juda pa àwọn tí wọ́n pa Amoni ọba, wọ́n sì fi Josaya ọmọ rẹ̀ jọba.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KEJI 33: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀