KRONIKA KEJI 14

14
Asa Ọba Ṣẹgun Àwọn Ará Sudani
1Nígbà tí Abija ọba kú, wọ́n sin ín sinu ibojì àwọn baba rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Asa ọmọ rẹ̀ jọba lẹ́yìn rẹ̀. Ní àkókò rẹ̀, alaafia wà ní ilẹ̀ náà fún ọdún mẹ́wàá. 2Asa ṣe ohun tí ó dára, tí ó tọ́, tí ó sì dùn mọ́ OLUWA Ọlọrun rẹ̀. Ó mú inú Ọlọrun dùn. 3Ó kó àwọn pẹpẹ àjèjì ati àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn kúrò, ó wó àwọn òpó oriṣa wọn lulẹ̀, ó sì fọ́ ère Aṣera. 4Ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ Juda láti wá ojurere OLUWA Ọlọrun àwọn baba wọn ati láti pa òfin rẹ̀ mọ́. 5Ó kó gbogbo àwọn pẹpẹ ìrúbọ ati àwọn pẹpẹ tí wọ́n ti ń sun turari ní gbogbo àwọn ìlú Juda jáde. Alaafia sì wà ní àkókò ìjọba rẹ̀. 6Ó kọ́ àwọn ìlú olódi sí ilẹ̀ Juda nítorí pé alaafia wà ní gbogbo ilẹ̀ náà. Ní gbogbo ọdún rẹ̀ kò sí ogun, nítorí OLUWA fún wọn ní alaafia. 7Ó bá sọ fún gbogbo ọmọ ilẹ̀ Juda pé, “Ẹ jẹ́ kí á kọ́ àwọn ìlú wọnyi, kí á mọ odi yí wọn ká pẹlu ilé ìṣọ́, kí á kan ìlẹ̀kùn sí àwọn ẹnubodè wọn, kí á sì fi àwọn ọ̀pá ìdábùú sí wọn. Ìkáwọ́ wa ni gbogbo ilẹ̀ náà wà, nítorí pé à ń ṣe ìfẹ́ OLUWA Ọlọrun wa. A ti wá ojurere rẹ̀, ó sì fún wa ní alaafia ní gbogbo ọ̀nà.” Wọ́n kọ́ àwọn ìlú náà, wọ́n sì ń ní ìtẹ̀síwájú. 8Asa ọba ní ọ̀kẹ́ mẹẹdogun (300,000) ọmọ ogun ní ilẹ̀ Juda, tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọ̀kọ̀ ati ọ̀kẹ́ mẹrinla (280,000) láti Bẹnjamini tí wọ́n di ihamọra pẹlu apata ati ọrun. Gbogbo wọn ni a ti kọ́ ní ogun jíjà tí wọ́n sì jẹ́ akọni.
9Sera, ará Etiopia, gbógun tì wọ́n pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà ẹgbẹrun (1,000,000) ọmọ ogun ati ọọdunrun (300) kẹ̀kẹ́ ogun. Wọ́n sì jagun títí dé Mareṣa. 10Asa jáde lọ láti bá a jà. Olukuluku tẹ́ ibùdó ogun rẹ̀ sí àfonífojì Sefata ní Mareṣa. 11Asa ké pe OLUWA Ọlọrun rẹ̀, ó ní, “OLUWA, kò sí olùrànlọ́wọ́ tí ó dàbí rẹ nítorí pé o lè ran àwọn ọmọ ogun tí wọn kò lágbára lọ́wọ́ láti ṣẹgun àwọn tí wọ́n lágbára. Ràn wá lọ́wọ́, OLUWA Ọlọrun wa, nítorí pé ìwọ ni a gbẹ́kẹ̀lé. Ní orúkọ rẹ ni a jáde láti wá bá ogun ńlá yìí jà. OLUWA, ìwọ ni Ọlọrun wa, má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni ṣẹgun rẹ.”
12Bẹ́ẹ̀ ni OLUWA ṣe ṣẹgun àwọn ará Etiopia fún Asa ati àwọn ọmọ Juda, àwọn ará Etiopia sì sá. 13Asa ati àwọn ogun rẹ̀ lé wọn títí dé Gerari. Ọpọlọpọ àwọn ará Etiopia sì kú tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò lè gbá ara wọn jọ mọ́; wọn sì parun patapata níwájú OLUWA ati àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Àwọn ọmọ ogun Juda sì kó ọpọlọpọ ìkógun. 14Wọ́n run gbogbo ìlú tí ó wà ní agbègbè Gerari, nítorí pé ẹ̀rù OLUWA ba àwọn ará ibẹ̀. Wọ́n fi ogun kó gbogbo àwọn ìlú náà nítorí pé ìkógun pọ̀ ninu wọn. 15Wọ́n wó gbogbo àgọ́ àwọn tí ń sin mààlúù, wọ́n sì kó ọpọlọpọ aguntan ati ràkúnmí wọn pada sí Jerusalẹmu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

KRONIKA KEJI 14: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀